Olorun n fe afurugbin - BNJCC - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, December 5, 2017

Olorun n fe afurugbin - BNJCC

Pasito Kehinde Aina ti ijo Kingdom Proclaimers Apostolic Ministry ti so pe awon okan to le furugbin ni Olorun n fe lati ba dowo po, ki ise e le tubo maa tesiwaju.

Alagba Awolude
Wolii Aina soro yi lakoko to n waasu nibi ayeye ajodun ikore ti ijo Cathedral Of The Blessed New Jerusalem Church of Christ (BNJCC), to wa ni Kuro niluu Abeokuta, ti won pe akori e ni "Ojo Ibukun Yoo Ro" (There Shall Be Showers of Blessings), eyi ti won se lojo Aiku Sande to koja yii.

Nigba to n soro lori koko iwaasu e to pe ni "Ayo Ibukun Ikore" pelu ese bibeli ti won fi sori akori ajo ikore naa, Esikieli 34:26 lo ti so opo merin to le ja si ayo ajodun ikore.

O so pe Ki eeyan to le kore, afurugbin gbodo wa, nitori pe bi ko ba si afurugbin, ko le si ikore, ati pe Olorun kii bukun ibi ti ofo ba wa, iyen ni pe ko si bi eeyan ti le mo adura a gba to, bi ko ba ti furugbin, ori ofo ni adura naa je.

Ninu oro e lo ti so pe "Olorun n fe afurugbin, kii se pe afurugbin owo (hand), bi ko se afurugbin okan (heart), nitori pe bi irugbin ko ba wa lati okan, owo ko le fi sile. Genesisi 4:3-16".

Wolii Aina tesiwaju pe ko le si afurugbin lai si irugbin gangan nitori pe irugbin ni afurugbin nilo lati gbin, ki a to le maa pe ni afurugbin.

Bakan naa lo tun so pe ile (land) ti afurugbin ba fe e furugbin e si naa tun se pataki ki afurugbin naa ma baa sise lori ofo. New lo so pe leyin gbogbo e, ojo ti yoo ro nigba ti afurugbin ba ti furugbin sori ile lo je pataki gbogbo e nitori pe bi ojo ko ba ro, irugbin ko le dagba.

Ninu oro alakoso ijo naa, Alagba S.O Awolude (JP) lo ti so pataki akori ajodun ikore todun yi pe odun Ibukun ni odun 2017 je, paapaa ninu ijo naa, ati pe awon ko le ka oore ti Olorun se fawon tan ninu ijo naa, tawon si gbodo dupe gidigidi lowo Olorun.

Awolude dupe gidigidi lowo igbimo eleni metadinlogun (17) to sagbateru ajodun ikore todun yi fun ise takuntakun ti won se lati je ki ayeye naa waye lara oto, tawon eeyan si n fogo f'Olorun latigba ti won ti bere.

Gege b'AWIKONKO se gbo, ojoru Wesde, ojo kokandinlogbon osu kokanla to koja yii ni won bere ayeye ajodun naa pelu isoji ita gbangba olojo meji, ati iso-oru ti iyin (Praise Night), nibi tawon agba olorin emi bii Beulah, Sir Muyen, Juliana Babarinde atawon min in ti forin yin Jesu, ko too di pe won pari ajodun naa lojo Sande ijeta, iyen ojo keta osu kejila.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI