E fura o, fufu oni majele ti po nita o - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, November 13, 2017

E fura o, fufu oni majele ti po nita o

Sunday Agbaje, Eko

Titi di bi e ti n ka iroyin yi loro fufu ti won lobinrin kan ra lagbegbe Ikosi, Ketu nipinle Eko to si yi pada di pupa si n je kayeefi fawon araadugbo Mende to wa lagbegbe Maryland nipinle Eko.

Fufu naa re o
Gege bi AWIKONKO se gbo, obinrin kan to n je Olasumbo la gbo pe o ra fufu lowo iya kan to n ta a nitosi oja igbalode to wa ni Ketu nirole ojo Aje, Monde ose to koja.

AWIKONKO gbo pe ogorun (#100) naira ni Olasumbo ra fufu meta, lero wi pe koun atawon ebi e le ri nkan je nigba toun ba de ile, lai je pe awon tun n se wahala lati da ina ale.

Nigba ti won so pe Olasumbo de ile lale ojo naa, ni okan lara awon omo e to ro pe fufu naa ko le to won sare lo o ra fufu min in, ki won le je aje yo.

AWIKONKO gbo pe nigba to di ojo keji, ti won maa pada loo wo fufu to ku nibi ti won ko o si, iyalenu lo je pe awo pupa ti yo sinu fufu naa, to si se won ni kayeefi.

Nigba to n b'AWIKONKO soro lati fidi isele naa mule, obinrin naa, Arabinrin Olasumbo so pe titi di boun se n ba de wa soro yi ni okan oun ko tii bale, nitori ninu fufu meta toun ra naa, meji loun je ninu e, lati pe eyokan to ku lo yi pada di pupa.

Olasumbo je ko ye wa pe omo oun koko so foun lojo keji wi pe o le je igbako ti won fi pon fufu naa lo se sii lara, ati pe awon ko sakiyesi e nitori pe o je ale ni, sugbon gbogbo oro yi ni ko wo obinrin naa leti, to si fa a to fi toju e.

O tesiwaju pe nigba to ma a di ojo Abameta Satide to koja yii toun tun pada loo wo fufu naa nibi tawon ko o si, o niyalenu lo je pe fufu naa ti yipada kuro ni awon funfun to wa, o si ti di pupa.

Ninu oro, o ni "Nigba ti mo n bo lati agbegbe Ikosi ni Ketu, ni mo ra fufu meta wi pe ki a le ri nkan je ti m ba dele. Nigba ti mo dele ni omo mi kan tun lo ra fufu min in ladugbo wa.

"Emi nikan ni mo je fufu naa, eyi ti omo mi lo ra lawon to ku je, ninu e naa ni oko mi ti je. Nigba to di ojo keji, a sakiyesi pe awo pupo wa lara e.

"A fi sile di ojo kerin ti a si tun rii pe o ti yi pada patapata di awo pupa. Latigba naa ni eru ti bere sii ba mi. Eyi lo je ki n pinu lati pada loo foro naa to iya ti mo ra fufu naa lowo e leti.

"Iyalenu lo je pe mi o ri mo. Igba ti mo beere lowo awon eeyan to wa nibe, won so pe o ti to ojo meta ti ko ti wa sibe. Oro naa ko ye mi mo rara nitori pe fufu ti omo mi loo ra ladugbo si wa bo se wa, ko yi pada."

Olasumbo lawon eeyan ti gba oun lorisirisi amonran wi pe koun tete loo se ayewo ni osibitu, koun si tun loo foro naa to awon olopaa leti lati sewadi obinrin to ta fufu naa foun.

O so pe bo tile je pe oko oun ti so pe koun ma pariwo sita, sugbon ti okan oun ko bale nitori pe oun fe kawon omo Naijiria maa fura lori awon nkan ti won ba n ra legbe opopona.

Ohun tawon to gbo sisele kayeefi naa n so ni pe fufu oni majele lobinrin naa ra, to si seese ko je pe awon kan to n fi eeyan soogun owo ni won tun n wa ona lati maa fi mu awon eeyan.

Bee lawon kan n so pe o seese ko je pe fufu kan soso to ni majele ni obinrin naa ko je yii, ati pe Eleda e to wa leyin e ni ko je ko je e.

Ni bayii, oun ta a gbo ni pe obinrin naa ti loo sayewo ni osibitu, to si tun ti lo lati fi to awon olopaa leti lati le sewadi iya oni fufu naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI