ORONNA: Isokan Yewa lo je mi logun - Oba Olugbenle - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, November 13, 2017

ORONNA: Isokan Yewa lo je mi logun - Oba Olugbenle

Oba Kehinde Gbadewole Olugbenle to je Olu Ilaro ati Oba alaye tile Yewa lapapo ti so pe isokan Yewa lo je oun logun ju ohunkohun lo, ati pe okan oun bale gidigidi lori awon omo Yewa nigba toun ko ba si nile.

Oba Olugbenle
Olu Ilaro soro yi lakoko to n gba awon igbimo ileese ibanisoro, MTN to n sagbateru ayeye odun Oronna lalejo ni Aafin Asade Agunloye to wa niluu Ilaro lai pe yi fun ipalemo ayeye naa.

Kabiyesi so pe latigba ti ayeye naa ti bere ni ife, alaafia ati isokan ti wo ilu Ilaro, eyi to mu ki ilu naa maa tesiwaju laarin awon ilu to ku kaakiri orileede yi.

Nigba to n gbawon omo Yewa lamoran, Oba Olugbenle so pe awon eeyan ko gbodo je ki asa ati ise ile naa parun latari esin ti won tewo gba lati odo awon oyinbo alawo funfun.

O so pe ile Yoruba nikan lo ni asa ati ise to se e fowo soya le lori nitori tinwon n fi iwa omoluabi se, ti won si n bowo fun asa pupo kaakiri awon eya to ku lorileede Naijiria.

Ninu oro ti e, alaga igbimo eto ayeye naa, Alaaji Rafiu Akinola so pe ona ara oto ni ayeye odun fe e gba sele latari awon eto olokan o jokan ti won ti la kale fun un, lati muu larinrin.

Akinola so pe eto naa ti yato si ti tele, ti ona ti won n gba se too si yato patapata, ati pe awon olorin lorisirisi ni won ti fiwe pe lati wa a dawon eeyan laraya, lara won ni Reminisce, Small Doctor, Chris Daniel atawon olorin min in ti gbogbo won je omo bibi Yewa.

O wa gbawon oloselu, paapaa awon to ti n gbero lati di ipo gomina nipinle Ogun lamoran wi pe ki won ma se lo anfaani ayeye naa lati fi se ipolongo idibo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI