Fatimo to ki foonu sinu obe si n gbategun lago olopaa - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, November 1, 2017

Fatimo to ki foonu sinu obe si n gbategun lago olopaa

"Ese mi jeje, mi o mon on mo" loro ebe to n jade lenu Arabinrin kan ti won poruko e ni Fatima Balogun, eni odun metalelogbon ti won loo fi foonu pamo sinu obe to gbe lo fun ale e to wa logba ewon Ibara niluu Abeokuta.

Fatimo
Kani obinrin naa mo pe oro naa yoo pada leyin ni, o seese ko ma ronu lati gbe ounje dani, depodepo wi pe yoo ronu lati fun oko e tele ni foonu.

Gege bi AWIKONKO se gbo, lojo Wesde ose to koja la gbo pe Fatima pinu lati loo wo oko e to n fe tele, ko to di pe o ba obinrin miran lo, Ganiyu Ajibode, eni ti won so pe o ti le losu mefa to ti wa logba ewon naa, leyin ti won fawon esun kan kan an.

A gbo pe omo meji ni Fatima bi fun Ganiyu ko to o di pe o loo fe obinrin min in, ti won si fija tuka lodun merin seyin, latigba naa ni won ko ti ri ara won mo.

Lai pe la gbo pe Fatima ronu kan baba awon omo e, to si wa a lo, sugbon Iyalenu lo je nigba to de odo awon ebi e, ti won si so fun un pe o ti wa logba ewon to wa ni Ibara niluu Abeokuta lati bii osu mefa, toun ko si tii lo yoju sii.

Idi ni yii ti won ni Fatima fi gbera lati adugbo Fagba, Iju Isaga nipinle Eko to n gbe, lati loo wo ololufe e tele naa logba ewon pelu ounje aladidun to tun gbe dani fun.

Ohun ta a gbo nipe bi Fatima se de odo awon to n so elewon, lo beere Ganiyu ati pe oun tun fe e gbe oun je fun in, lesekese lawon woda naa ti gba ounje naa lowo e, ti won si yee wo.

Iyalenu lo je fun nigba ti won ri foonu ninu kula to bu obe sii, ti won si pariwo e sita, ko too di pe won pe awon olopaa lati wa a muu nitori ti won so pe nnkan to se lodi si ofin to de ileese won.

Nigba toun naa n soro, Fatima so pe asise nla gba a loun se nitori pe kani oun mo pe asiri maa tu sita ni, oun ko ba ma ti se nnkan to je be e, ati pe oun ko mo pe nnkan toun se Lodi si ofin.

Fatima tun so pe bo tile je pe ololufe oun tele naa ko so pe koun mu foonu naa wa, sugbon lati le maa ba a soro loun se dogbon naa lai mo pe Asiri maa pada tuu. Bee lo rawo ebe pe ki won dariji oun.

Lati fidi ise naa mule, Agbenuso fun ileese olopaa ipinle Ogun, Abimbola Oyeyemi nigba to n b'AWIKONKO soro laaro ojo Fraide to koja yi, o so pe atimole awon olopaa Ibara lo si wa, won ko tii gbe wa sodo awon ni Eleweran lati tubo foro wa lenu wo.

O ni leyin tawon ba foro wa a lenu wo tan lawon yoo to o mo boya kawon foju bale ejo tabi kawon fi sile, sugbon toun mo pe oro e yoo ti ko awon araalu logbon.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI