Lucky to n foruko Mike Adenuga lu jibiti ti ha o - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, November 22, 2017

Lucky to n foruko Mike Adenuga lu jibiti ti ha o

Oruko ko ro odomokunrin eni odun merinlelogun (24), Lucky Ehioboh ti won lo n foruko gbajugbaja onisowo ile Afrika nni, Ogbeni Mike Adenuga lu jibiti ko ro o mo nigba towo olopaa ipinle Ogun te e lose to koja, to si bere sii bebe pe ki won se oun jeje nitori pe ise esu ni.

Lucky
Gege b'AWIKONKO se gbo, won ni ori ero ayelujara abanidore kan ti a mo si Facebook ni Lucky ti won ni omo bibi ipinle Edo ni ti n lu awon eeyan ni jibiti owo, ati pe oruko gbajugbaja onisowo Mike Adenuga lo fi n lu awon eeyan ni gbajue naa.

Nigba tasiri odomokunrin Lucky yi maa tu, okunrin kan ti won poruko e ni Abiodun Olalekan Ogunseye lo lu ni jibiti owo to fi die le ni milionu kan (1,028,770) naira.

A gbo pe se ni Lucky pelu oruko ati Foto Adenuga lo fi paro fun Olalekan wi pe oun yoo ba a wa ise si eka ileese epo robi, iyen Nigeria National Petroleum Company (NNPC), ti o ba ti le san milionu kan aabo naira, sugbon ti okunrin naa ko ro o lemeeji pe bo ya won fe e gba oun ni.

Lesekese ni Abiodun ti so pe oun yoo san ninu owo naa, ati pe ti ise naa ba ti bo si tan, loun yoo to o san eyi to ku, ki o le tete je ki ise naa ya, nitori ta a gbo pe Lucky ti so fun un pe awon alase ileese NNPC naa loun fe e fowo di lenu ki won le gba a si ise.

AWIKONKO gbo pe bi Abiodun Olalekan se san owo naa tan, loju e sese to o la wi pe won ti fi Eko han oun lori ero ayelujara, to si fibinu loo foro naa to awon olopaa leti.

Ko pe ti won fi so pe awon olopaa rowo to Lucky nibi to n gbe, nitori ti won so pe ojo Aje Monde, iyen ojo kefa osu yii lowo te.

Iyalenu lo tun je pe nigba ti won maa loo ka Lucky naa mole, foomu olowo nla (iPhone) mefa, ero ayarabiasa komputa kan, sim card mejo ati kaadi ATM orisi banki marun un ni won ba ninu ile e to fi n lu awon eeyan ni jibiti ki asiri e ma ba a tete tu sita.

Ni bayii, ohun ta a gbo ni pe, Komisana olopaa, Ahmed Iliyasu ti seleri wi pe ileese won yoo foju Lucky ba ile ejo leyin tawon ba tubo paro ise iwadi won nitori wi pe aimoye awon eeyan lo seese ko ti pa lekun.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI