Nitori iwa ilara ni Rose se fi bileedi fa omo oko e lara ya - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, November 22, 2017

Nitori iwa ilara ni Rose se fi bileedi fa omo oko e lara ya

Titi di bi e ti n ka iroyin yi ni odaju abiyamo kan, Rose James Michael ti won loo fi bileedi fa omo oko e, Blessing James Michael, omodun mejo lara ya si n gbategun logba ileese olopaa ipinle Ogun.

Rose
Gege bi AWIKONKO se gbo, ojo Tosde ojo kesan an osu yi la gbo pe Rose ti won so pe ojule mewaa, adugbo Onafowokan, Ita-Oluwa lagbegbe Ogijo, opopona Sagamu, Ikorodu sise buruku naa.

Esun ti won so pe Rose fi kan Blessing ni pe o se omo oun lese, toun si gbodo gbesan lara e pada, eyi lo fa a ti won fi so pe Rose fibinu lu omo naa nilukulu.

A gbo pe ko too di pe Rise huwa odaju  yi, nise lo koko pe oko e, Ogbeni James Michael lati fi ejo sun, ati pe oun yoo gbesan ko too de. Gbogbo ebe ti won so pe James n be iyawo e Rose ni won so pe ko wo eti e.

Lara awon araadugbo naa to b'AWIKONKO soro so pe odaju abiyamo paraku ni Rose ati pe iya lo ma fi n je Blessing ti oko e ko ba ti si nile, bee ni ko tun maa n fun lounje lasiko.

Blessing
Obinrin naa to so pe ka foruko boun lasiri so pe awijare lasan ni Rose n so wi pe omodebinrin naa se omo e lese, nitori pe o ti n wa ona lati seku pa Blessing, sugbon ti ko ri aaye.

Bee la tun gbo lojo naa, gbogbo bawon eeyan se n be Rose lasiko to n lu Blessing ni ko wo o leti, titi to fi mu omo naa wole, to si bere sii fi bileedi ya lapa ati ese.

AWIKONKO gbo pe bawon araadugbo se ri Blessing ninu agbara eje ni won ti sare gbe e lo si osibitu Lenard to wa ni Ogijo, ti won si ranse pe oko e pe wahala ti sele.

Nigba ti James de to ri ipo ti omo naa wa, lo ba bere sii luu, sugbon awon eeyan ni won so pe ko loo foro naa to awon olopaa leti, eyi lo fa a to fi wo Rose lo si tesan lati loo fa le awon olopaa lowo.

Ogbeni Peter Williams to so pe ileewe toun ti n sise oluko ni Blessing n lo nigba to n b'AWIKONKO soro so pe iyalenu loro Rose si n je fawon, ati pe lara awon oluko nileewe naa maa n ra nkan fun Blessing nitori pe kii se gbogbo igba lo maa n jeun wa.

Apa Blessing
Agbenuso fun ileese olopaa, Abimbola Oyeyemi nigba to n soro so pe bo tile je pe omo naa si wa ni osibitu nibi to ti n gba itoju, sibe Komisana won ti tare Rose si eka ileese olopaa to n ri si fifi omo se oowo eru ati lilo omo nilokulo (Anti Human Trafficking and Child labor Unit of Criminal Investigation and Intelligence Department)

O wa seleri wi pe dandan ni ki obinrin naa foju ba ile ejo lati jiya ese e labe ofin, bee lo gbawon araalu lamoran wi pe ki won ma se pa iwa ibaje mora.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI