Ka
ni Robert Mugabe to je Aare orileede Zimbabwe tele lo iseju kan sii ko to o
kowe ifipo sile gege bi Aare ranse si igbimo alase (Parliament) orileede naa
ni, nkan ti a ko yi ko ni a o ba maa ko.
Gege
b'AWIKONKO se gbo, lasiko tawon igbimo alase (Parliament) naa n se ipade lori
ona ti won yoo fi le Mugabe kuro lori ipo ni leta naa te won lowo, ti gbogbo
won ko si mo nkan ti won le se mo.
Yato
si ipade ti won n se lowo yi, AWIKONKO gbo pe ogunlogo awon omo orileede naa ti
gbaradi lati se iwode ifehonuhan lati le Mugabe to ti je gege bi Aare orileede
naa lati odun metadinlogoji (37) seyin kuro lori ipo, ati pe won fe e ko kowe
fipo naa sile.
Lakoko
naa oniroyin te won lowo pe erongba won ti wa si imuse ati pe iwode ti won n
gbero lati se yoo pada di ariya repete mo won lowo.
No comments:
Post a Comment