Obasanjo, Alake fowo soya lori Giwa FUNAAB tuntun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, November 2, 2017

Obasanjo, Alake fowo soya lori Giwa FUNAAB tuntun

Aare tele ri lorileeede yii, Oloye Olusegun Obasanjo ati Alake tile Egba, Oba Michael Adedoyin Aremu Gbadebo ti fi owo soya lori Giwa (Vice-Chancellor) tuntun ti ileewe to n ko eko nipa ise ogbin, iyen Federal University of Agriculture, Abeokuta (FUNAAB) sese yan, Ojogbon Felix Kolawole Salako.

Ojogbon Salako
Gege bi AWIKONKO se gbo ni atejade ti awon alase ileewe naa fi ranse si wa, a gbo pe lakoko ti won n gbe opa ase fun Ojogbon Salako ni Oloye Obasanjo to tun je Balogun ilu Osu, Abeokuta ati Oba Gbadebo ti gboriyin fun okunrin naa, wi pe awon ni idaniloju wi pe yoo gbe ileewe naa gun oke agba.

Oloye Obasanjo ninu oro e so pe pelu awon iwe eri ti Ojogbon Salako ni, oun le fi gbogbo enu so o wi pe iru awon eeyan ti ileewe naa nilo lasiko yi niyen, toun si nigbagbo wi pe yoo se daadaa ju nnkan teeyan lero lo.

Ninu oro ti e, Alake tile Egba so pe leyin tawon ye e wo tan, to si ti la opolopo idanilekoo koja, to tun peregede nibe, ko si ani-ani nipa wi pe yoo se daadaa, nitori pe o kun oju osuwon, o si tun mo nkan to n se.

Bakan naa ni eni to je gege bi Pro-Chancellor ileewe naa, Dokita Aboki Zhawa so pe ilana ti won fi yan Ojogbon Salako je ona to ye ki won to gege, to si se e fowo e soya, nitori pe oun nikan lo peregede julo laarin awon to dupo naa.

Dokita Zhawa wa ro awon osise patapata atawon akekoo lati fowosowopo pelu ijoba Ojogbon Salako, lati le je ki awon ise to ba dawo le yori si rere nitori pe agbajowo nikan lo le gbe eru sori.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI