Won ni iku Jide omo Tinubu kii soju lasan o - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, November 2, 2017

Won ni iku Jide omo Tinubu kii soju lasan o

Bo tile je orisirisi lawon araalu to gbo soro iku akobi Oloye Bola Tinubu to je asiwaju agbegbe oselu APC lorileeede yii n so nipa nnkan to sokun fa iku Jide Tinubu, sibe ohun ta a gbo ni pe aisan okan (heart attack) lo seku pa a lojiji.

Asiwaju Tinubu
Gege bii iroyin to te AWIKONKO lowo, a gbo pe ni nnkan bii ago mesan an ale ojo Isegun Tusde to koja yi, iyen ojo kojanlelogbon ni won so pe Jide to je omodun metalelogoji deede subu lule, to si gbabe ku.

Ere la gbo pe awon toro naa soju won koko pe e, nitori ti won so pe won si n bawon ti won jo wa papo dapara lowo, ko too di pe o sare di igba aya e mu, to si subu lule.

Lesekese la gbo pe won ti sare gbe e lo si osibitu kan to wa ni Lagos Island, sugbon nigba ti won maa fi de be, akuko ti ko leyin omokunrin naa, ti won si so fun won ni osibitu pe oku ni won gbe wa.

Nibi ipade awon oloye egbe oselu APC ti won se nilu Abuja la gbo pe baba e, Ahmed Tinubu wa, ti won ko si gbe iroyin naa sii leti, oku oru la gbo pe won se oro iku e, sugbon nigba to pada de ilu Eko lojo Wesde ni won sese soro naa jade sita.

Awon to sunmo ebi Tinubu to je ka mo bo se n lo so pe nise lawon eeyan sare di Tinubu mu, nitori pe die lo ku ko subu lule nigba to gbo iroyin akobi omo e naa, eni ti won so pe o feran lati maa pa awon eeyan lerin.

Titi di bi a se sakojopo iroyin yi tan, mosuari osibitu kan ta a foruko bo lasiri la gbo pe won gboku naa si, lati se ipalemo bi won yoo se sinku Jide Tinubu to je okan lara awon agbejoro lorileeede Naijiria.

Bakan naa la gbo pe opo awon eeyan ja-nkan-ja-nkan lorileeede yi ati kaakiri agbaye, to fi mo awon oloselu atawon abanikedun lo ti bere sii lo ki Oloye Bola Tinubu nile, lati ba a kedun, bee lawon ti ko si nitosi naa n fi ateranse ibanikedun ranse si agba oloselu naa.

Lara awon to ti ba idile Tinubu kedun ni Aare Muhammadu Buhari, Ojogbon Yemi Osinbajo, Gomina Orton, Ogbeni Femi Adesina, Oloye Femi Fani-Kayode, Otunba Gbenga Daniel, Gomina Ibikunle Amosun, Otunba Rotimi Paseda, Gbogbo ile igbimo asofin agba lorileede yi, Gomina Abiola Ajimobi atawon min in.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI