Obasanjo ni kawon oloselu se jeje - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, November 22, 2017

Obasanjo ni kawon oloselu se jeje

Sunday Agbaje

Aare teleri lorileede yi, Oloye Olusegun Obasanjo ti so gbawon oloselu orileede yi lamoran wi pe ki won se jeje nitori pe eto oselu ko ye ko je nkan to n la iku lo.

Obasanjo soro yi lai pe yi niluu Calabar nipinle Cross River nibi ayeye ifilole iwe tuntun kan ti won pe akole e ni "Stepping Forward with Uti J.D. Agba", eyi ti Goddy Jeddy Agba ati Mathias Okoi - Uyouyo ko.

Oloye Obasanjo to tun je Balogun Owu niluu Abeokuta, eni to je alejo pataki ojo naa je ko di mimo pe oloselu to ba ni ijakule lakoko eto idibo gbodo gba kamu ni, ko si tun fowosowopo pelu eni to ba jaws olubori lati le je ki alaafia wonu ilu wa.

Ninu oro e, o so pe "Oro oselu ko ye ko je emi ati iku. Eni ti ko ba olori awon iranse, ko le je igbakeji olori awon iranse, nitori pe olori awon iranse ko le da ise naa se. O gbodo fowosowopo pelu awon min in."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI