Awon olopaa koju ija sawon akekoo l'Osogbo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, November 22, 2017

Awon olopaa koju ija sawon akekoo l'Osogbo

Tolu Ogunlana


Titi di bi e ti n ka iroyin yi lowo ni ileewe Osun State College of Education to wa nilu Ila Orangun, nipinle Osun si n gbona janjan lowo latari bawon olopaa se pa awon akekoo meji ileewe naa lojo Aje Monde ana.

Gege b'AWIKONKO se gbo, won ni awon akekoo ileewe giga kaakiri ipinle Osun ni won dide ifehonuhan alaafia sijoba lati tako ipinu ti won sese se nipa owo ileewe won ti won tun fowo kun, eyi ti ko dun sawon akekoo naa ninu.

AWIKONKO gbo pe ikorita kan to gbajumo, iyen ikorita Olaiya lawon akekoo naa ti ko ara won jo, ko too di pe won bere iwode naa. Agbegbe Gbongan si Osogbo la gbo pe awon akekoo naa gba, ti won si n korin bu ijoba ipinle naa wi pe ko se daadaa nipa owo ileewe won ti won tun fowo kun.

A gbo pe bawon olopaa se ri won, ni won ti yin ibon tajutaju (tear gas) si won loju, ti won tun yin in fun Azeez to je akekoo Ila Orangun leka ikekoo Oyinbo, bee ni won tun fo kini naa mo Femi lori, ti won si sare gbe won lo sile iwosan fun itoju oju won.

Ohun ta a gbo ni pe osibitu ti won koko gbe Femi ni won ti so pe awon ko le se e, to fa a ti won fi pada gbe e lo si osibitu olukoni ti Obafemi Awolowo (Teaching Hospital) nibi to ti n gba itoju lowo.

Lara awon akekoo nileewe gbogbonise ti Iree, iyen Osun State Polytechnic so pe egberun merinlelogbon (#34,000) lowo ileewe tawon n san tele, sugbon ti won ti so pe egberun marundinlaadorin (#65,000) naira lawon yoo tun maa san bayii.

Se lawon akekoo naa kominu lori ipinu ijoba ipinle Osun pelu igbese naa, ati pe won tun so pe ipinu naa ko bojumu latari bijoba tun se je awon obi won to n sise labe ijoba naa lowo osu, ti won ko si tun fowo kun owo osu won.

Ogbeni Saheed Afolabi to je pe igbakeji oludari egbe akekoo nile Yoruba nigba yo n jeri soro naa so pe iwa tawon olopaa naa ku die kaato nitori pe nise lo ye ki won wa ona min in lati da si oro naa, di pe ki won yinbon tawon tajutaju lu awon akekoo to je pe eto won ni won n ja fun.

Nigba to n tako esun awon akekoo naa, Komisana foro iroyin ati bo se n lo nipinle Osun, Ogbeni Adelani Baderinwa so pe aheso ti ko lese nile lasan ni won n so pe ijoba fowo kun owo ileewe nipinle naa.

O lawon to sese fe e wole sawon ileewe giga kaakiri ipinle naa lo je pe won yoo san awon owo kan tijoba sese se ipinu e jade sita ati pe ko kan awon to ti n kekoo lowo.

O wa tun je ko di mimo pe ijoba Ogbeni Aregbesola yo je gomina won lo din owo awon ileewe ku si iye ti won n san tele nigba to gba opa ase gege bi gomina lodun 2011.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI