Won fee yo adele oga agba Mapoly, Ayodeji Tella - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, November 6, 2017

Won fee yo adele oga agba Mapoly, Ayodeji Tella

Pelu bi nnkan se n lo nileewe giga gbogbonise Moshood Abiola, MAPOLY ti won tun ti so di Moshood Abiola University of Technology, MAUSTECH bayii, afaimo ni kawon oluko agba atawon osise patapata ma dana oro fun Adele oga agba (Acting Rector), Ogbeni Sulaiman Ayodeji Tella ti gomina Ibikunle Amosun tipinle Ogun loun yan, leyin to da oga gba nibe tele, Ojogbon Oludele Itiola duro ni tipatipa.

Ko si n kan meji to fa a bi ko se bi won se so pe okunrin naa ko niwe eri to kun oju osuwon lati di oga agba nileewe naa, ati pe ko seni to le so lato ile to ti jade, ti won si tun so pe etanu ni Gomina Amosun fi yan an sibe latari wahala ti agbarijo awon osise nileewe Poly, iyen ASUP n ba ijoba fa lori ona ti won gba da MAUSTECH naa sile.

Be o ba gbagbe, ojo keta osu mewaa to koja yii ni Gomina Amosun ni ki Ojogbon Otiola lo jokoo ifeyinti (terminal leave) sile e, ki Ogbeni Tella si lo o ropo e digba ti wahala naa yoo fi wa sile, o si seese ko je pe oun ni won yoo maa lo lo.

Latigba naa lawon osise atawon agbaagba nileewe poli naa ti n beere lowo okunrin naa wi pe ko ko awon iwe eri to ni sile ati itan mipa igbesi aye e sile, kawon le mo boya o kaju eni ti le fi se aga agba le won lori.

Fawon to ba mo ileewe MAPOLY naa daadaa, yoo mo pe ko din ni marundinlogota (55) lawon to niwe eri PhD nibe, lai ka awon to sese gnoye PhD  ni fasiti FUNAAB lose meta seyin nibi ayeye ikekoo jade (convocation) ti won se.

Gege bi iroyin to te AWIKONKO lowo lati nnkan bi ose meji seyin se so, a gbo pe oga agba ileewe girama kan ni Ogbeni Tella tele, ko too di pe Gomina Amosun lo pe e, ti won si so pe okunrin naa ko niwe eri Masters Degree.

AWIKONKO gbo pe gbogbo akitiyan awon osise lati je ki okunrin naa ko awon iwe eri to ni sile lo n ja si pabo titi dasiko ta a sakojopo Iroyin yi tan nitori ti won so pe se lo n fi ojo kun ojo fun won, ati pe kii se gbogbo igba lo n yoju sileewe naa nitori e.

Lati fidi oro naa mule, AWIKONKO gbiyanju lati ba agbenuso ileewe naa, Ogbeni Sulaiman Adebiyi soro lo ja si pabo, ti ko si tun da atejise wa pada titi dasiko taa sakojopo iroyin yi tan.

Bee la gbo pe awon osise naa tun ti gun le iyanselodi ni tipatipa, bo tile je pe oni ojo Aje Monde ni won so pe idanwo to ti ye ko bere lati bi osu meji seyin bere, sugbon nitori pe Gomina Amosun ko tii dawon lohun nnkan ti won n fe lati odo ijoba lo fa a.

Okan lara awon oluko to b'AWIKONKO soro laaro ojo Satide to koja yii, eni taa foruko bo lasiri so pe awon ko tii mo igba tawon yoo pada wole, nitori pe bi Gomina Amosun ko ba dawon lohun, ko si ise ati pe lara nnkan tawon n fe ni pe ki Amosun je kawon si maa lo Abeokuta digba ti won yoo pari Ipokia.

Won ni agidi e lo fa a to fi ba eto Eko je nipinle Ogun, to si n so pe obitibiti owo lawon n na lori eto Eko, sugbon tawon eeyan ko ri koko e.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI