Awon adigunjale kolu ileese Dangote n'Ibese - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, December 5, 2017

Awon adigunjale kolu ileese Dangote n'Ibese

Kani kii se pe awon olopaa tete gbe igbese lai foro naa para rara, o see se kawon adigunjale to yawo ileese Dangote to wa niluu Ibese nitosi Ilaro sise won laseyori lojo naa, ki won si tun na papa bora.

Aaro ojo Abameta Satide to koja yi la gbo pe awon adigunjale to to meje ko ogun loo lati ja ileese naa, nibi ti won ti n se simenti lole, sugbon towo palaba awon meji pada segi.

Ohun ta a gbo ni pe bawon adigunjale naa se wole ni won ti loo dawon sikioriti ti won ro pe o see se ki won di won lowo ise dubule, sugbon ti lara awon sikioriti naa sare tawon olopaa to wa ninu ogba ileese naa lolobo.

Ninu awon adigunjale naa la gbo pe won ti kori si ibi ti won n ko awon irinse si nileese naa lati loo ko awon eru nibe.

AWIKONKO gbo pe awon olopaa naa ni won ti gbera nibi ti won wa lesekese lati wa a koju won, sugbon iyalenu lo je pe bawon adigunjale naa se ti foju kan awon olopaa ni won ti sare koju ibon si won, ti won si foro naa se eni to yara ni oogun n gbe.

Awon olopaa naa ko foro naa fale tawon naa fi bere sii yinbon ti won, ko to o di pe won pa okan lara won lesekese, tawon to ku si gbiyanju lati salo, nibe nibon tun ti ba elomin in lara won.

Lara awon toro naa soju e to gbe iroyin isele naa s'AWIKONKO leti so pe o see se ko je pe awon eru ti won sese ko de sileese naa ni won wa a ji ko, ati pe o le je pe lara awon to.n sise nibe lo fawon odaran naa lowo.

Nigba to n fidi oro naa mule, Agbenuso fun ileese olopaa ipinle Ogun, Abimbola Oyeyemi so pe bo tile je pe awon to ku na papa bora, sugbon o seni laanu wi pe eni kan tibon ba ninu awon meji naa, eni tawon ti n nigbagbo wi pe yoo so idi ti won fi wa a jale naa fawon tun ta teru nipa.

O je ko di mimo wi pe lakoko ti n gbe e lo si osibitu lati toju e lo dake, to si dagbere faye, ati pe ninu awon to salo naa gbe ota ibon lo, sibe o ni iyen ko di ise iwadii won lowo.

AWIKONKO tun gbo pe ibon single barrel kan pelu awon ota ibon merinla atawon eroja lorisirisi ti won fi n fo ile ni won ri gba lowo won.

Ni bayii, Ahmed Iliyasu to je Komisana olopaa ti wa a ro awon araalu wi pe ki won tete fi to awon olopaa leti bi won ba sakiyesi eni ti won kofiri ogbe Ota ibon lara e, to si seleri eto aabo to peye fawon eeyan bi ayeye odun keresimesi se n wole bo.


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI