Bi Ayeye Ogun Odun Ti Yinka Ayefele N'ijamba Moto Yoo Se Lo Niyii - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, December 12, 2017

Bi Ayeye Ogun Odun Ti Yinka Ayefele N'ijamba Moto Yoo Se Lo Niyii

Gbogbo eto lo ti pari bayii fun ti ayeye ogun odun ti gbajumo olorin igbagbo nni to filu Ibadan se ibugbe, Dokita Yinka Ayefele (MON) yoo se lo, bere lati oni ojo kejila osu kejila.

Be o ba gbagbe, ojo kejila osu kejila odun 1997 ni Yinka Ayefele pade ijamba moto to ku die ko gba emi e loju ona Abeokuta siluu Ibadan, sugbon to je pe ori aga aro lo pada ja a si, latigba naa ni ko ti le fi ese e rin mo.

Bo tile je pe opo awon eeyan to gbo nipa ijamba moto ti Yinka Ayefele ba pade lodun naa lohun ni won ro pe o maa seku pa a, sugbon ti Olorun fi ijamba naa se ategun sibi igbega e, nitori latigba naa lokiki e si ti n kan kaakiri agbaye titi dasiko yi.

Gege bi iroyin to te AWIKONKO lowo se so, eto ose kan gbako ni omo bibi ilu Ekiti naa ti kale lati fi se ayeye naa, ko da, ti a tun gbo pe yoo tun lo anfaani e lati gbe rekoodu tuntun to pe ni "Living Testimony" jade.

Oni ojo kejila gangan ni eto naa bere ni pereu ti yoo si pari lojo ketadinlogun osu yii.

AWIKONKO gbo pe Ayefele atawon ore e yoo teko leti laaro oni lo si ilu Ipoti, nipinle Ekiti ti won ti bii lati loo se ifilole gbongan ayeye olowo iyebiye, eyi to ko fun ileewe girama Ipoti to lo, iyen Ipoti High School.

Bi won ba se n kuro nibe ni yoo tun maa lo anfaani ajo to n seranwo fawon eeyan, iyen Yinka Ayefele Foundation lati se iranlowo fawon obinrin ti ko din ni ogorun (100), nipa riro won lagbara pelu owo atawon ebun ti won le maa lo lati fi sise ti ara won.

Ohun ta a tun gbo ni pe laarin ose yi bakan naa ni Yinka Ayefele atawon iko akoworin e yoo tun maa sabewo sawon ile awon omo ijoba (orphanage homes), ile awon arugbo ati osibitu kaakiri, paapaa osibitu ileeko to wa niluu Ibadan, iyen University College Hospital (UCH) nibi ti yoo ti maa fun won lawon ebun bii boosi, owo, ounje atawon nkan min in.

Ojo Aiku Sande to m bo yi, iyen ojo ketadinlogun ni won yoo pari ayeye naa pelu isin idupe ologo, nibi ti yoo tun ti maa se ifilole ati ikojade iwe akoko to ko, eyi to pe akole e ni "You And Your Spine", ninu ile orin e, Ayefele Music House, Challenge niluu Ibadan.

Bakan naa ni yoo tun maa se ikojade akanse rekoodu tuntun to fi n seranti ogun odun naa to pe Living Testimony, ti yoo si tun maa gbe fidio awon rekoodu to ti se tele, iyen Fresh Glory ati Upliftment jade.

AWIKONKO wa n fi asiko yi ba Yinka Ayefele yo fun awon aseyori e laye, ti a si n gba ladura pe yoo tubo se eyi to ju yi lo. Fun awon ti ko ba mo, ko si olorin meji ti Olootu iroyin AWIKONKO feran bi ko se Yinka Ayefele, lati odun 1998 lo si ti n gba ti okunrin naa titi dasiko yi.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI