Idagbasoke ipinle Osun ati ilosiwaju awon odo lo je mi logun - Tunde Eso - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, December 11, 2017

Idagbasoke ipinle Osun ati ilosiwaju awon odo lo je mi logun - Tunde Eso

Oludije sipo gomina nipinle Osun lodun 2018 to m bo, Ogbeni Tunde Eso ti je ko di mimo pe idagbasoke ipinle naa, ati aseyori awon odo lo je oun logun ju, eyi to mu oun pinu lati dupo naa lodun 2018.

Tunde Eso soro naa lai pe yi lakoko to n ba oniroyin soro nipinle naa latari awon ipinu to ni lati dupo gomina naa lodun to n bo yii labe egbe oselu Peoples Democratic Party, PDP.

Eso to tun je oludasile ajo aladani (NGO) lati satunto orileede yi, iyen ajo to pe ni FIX NIGERIA GROUP so pe bo tile je pe oun ko tii di ipo kankan mu ninu oselu ri, sugbon toun ti di orisirisi ipo ti ko nii se pelu oselu mu.

O so pe itara toun ni lati fi sin awon eeyan oun nipinle Osun lati je ki gbogbo won ni anfaani kan naa nitori toun ti se orisirisi nkan lati yi awon eeyan pada si rere lo fa a toun tun fi fe e tesiwaju.

Tunde Eso to ti ko orisirisi iwe bii Vision for Afrika, to si tun abala oro iyanju lawon iwe iroyin kaakiri orileede yi so pe bi awon omo ipinle naa ba fi aaye gba oun, ilopo awon nkan meremere toun ti n se tele loun yoo tun se, ti won ko si bii kabamo pe won dibo yan oun.

O tesiwaju pe opo awon akekoo ni won yoo je anfaani eto eko ofe, ironilagbara, ibowo fori ade, iyen awon Oba alaye, ina ijoba ti kii seju, idasesile, eto aabo to pe ye atawon ohun amayederun fawon araalu.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI