E ma je kawon oloselu rii yin gege bi alatako – Wole Sokunbi - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, December 21, 2017

E ma je kawon oloselu rii yin gege bi alatako – Wole Sokunbi

Alaga egbeawon oniroyin nipinle Ogun, Komureedi Oluwole Sokunbi ti gbawon oniroyin ori ero ayelujara, iyen awon Bloggers orileede Naijiria labe aburada egbe National Association of Nigerian Bloggers (NANB) lamoran wi pe ki won ma se je kawon oloselu ri won gege bi alatako nigba ti won ba n gbe iroyin won jade.

Wole Sokunbi
Sokunbi soro yi lojo Aje Monde to koja yi lakoko to bawon omo egbe NANB naa soro nibi idanilekoo to waye ninu gbongan awon oniroyin naa to wa niluu Abeokuta, ipinle Ogun.

Alaga naa so pe bo ti le je pe asiko yi gan an lawon oloselu nilo won pupo, sugbon tawon naa si gbodo fogbon se e, ti won ko gbodo koroyin won lati tako oloselu Kankan, bi ko se pe ki won fi oro oselu sile fawon oloselu lati maa ba ara won fa oro oselu won, kawon naa ma si titori nkan ti won maa je, ki won di oloselu ojiji.

O ni gbogbo oniroyin ori ero ayelujara (bloggers) ni won se pataki pupo lati mu idagbasoke ba orileede paapaa orileede Naijiria nitori pe odo won lawon eeyan ti maa n koko ka iroyin, ko to o di pe awon oniwe iroyin rii lati sise lori e.

Komureedi Sokunbi tesiwaju wi pe bo tile je pea won kan wa to je pe iroyin ti won ba ti koko gbe lawon eeyan yoo koko gbagbo, bo tile je pe iro lo wa ninu e, ko too di pe awon eeyan ri otito oro nibe, sugbon ki atunse too wa, ona a ti jin.

Okunrin naa tun je ko ye awon omo egbe NANB wi pe anfaani nla lo maa je foun lati ni awon eeyan naa laarin won, nitori pe ojo ti pe toun ti n wa won lati mo won, sugbon ti inu oun dun nigba ti won koko wa a fara ha noun ninu ofiisi wi pe awon niyii.

O ni idi niyii toun tun fi lo soro naa fawon egbe oun toku nibi ipade tawon se niluu Uyo wi pe oun ti ri awon omo egbe oniroyin ori ero ayelujara (bloggers) labe asia egbe NANB, tqwon yen naa si fi idunnu ati ayo so wi pe nkan to dara ni, ati pe bi won ba jade lati ara egbe oniroyin, iyen NUJ ni ko ba ti dara ju.

Sokunbi wa seleri wi pe lai pe oun yoo pin won soto lati le je ki won da duro, kawon naa si le maa ri awon anfaani ati mudun-mudun to ba ye je lati odo awon eeyan jan-kan-jan-kan laarin ilu.

Ninu oro ti e, alaga eka egbe oniroyin ti won pe ni Correspondents’ Chapel, Komureedi Wale Adewumi so pe ki won ma ro pe owo wa ninu ise iroyin, nitori naa ki won ri ise naa gege bi nkan ti won ni itara fun, nitori pe nkan to le je keeyan saseyori ni itara teeyan ba ni si nkan.

O ni ti won ba mo awon eeyan to joju lawujo lo le je ki won tete saseyori nitori pe eeyan ni n gbe eeyan nigbowo, paapaa lasiko ti won ba nilo nkan, awon ni won le lo sa ba lati gba won sile.

Nigba toun naa n soro, Komureedi Habeeb White to tun je amofin so pe o dara ki oniroyin mo nkan to n se, ko ma ba a bo sinu wahala ifesunkan, nitori pe orisirisi esun ayederu iroyin ni won ti gbe wa siwaju oun, toun si ti da si.

Whyte so pe boun ti se sin awon oniroyin kan lo sewon, be e naa loun ti gbawon kan sile latari ayederu iroyin ti won gbe e naa ni, nitori naa lo se pe kawon eeyan naa lo rii daju wi pe won n topinpin awon iroyin ti won yo maa gbe jade.

Aare fidihe egbe naa, Komureedi Solanke Taiwo nigba toun naa soro dupe gidigidi lowo alaga awon oniroyin, Komureedi Sokunbi ati alaga eka oniroyin, Komureedi Adewumi fun asiko ti won fi sile gbawon lalejo, ti won si tun se idanileko fun won, pelu awon ileri ti won tun se fun won.

Solanke so pe bo tile je pe oun ko nii se ileri idaniloju, sugbon toun nigbagbo wi pea won yoo jo won loju ju bi won ti se lero lo nitori pe loorekoore lawon yoo maa sepade lati mu idagbasoke ba egbe NANB paapaa awon oniroyin ori ero ayelujara.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI