Olorun ni olori alaabo - Adedoyin VGN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, December 24, 2017

Olorun ni olori alaabo - Adedoyin VGN

Adari egbe Fijilante orileede Naijiria, eka tipinle Ogun, Vigilante Group of Nigeria (VGN), Komanda Nureni Olanrewaju Adedoyin ti so pe Olorun nikan ni olori alaabo emi ati dukia gbogbo eeyan, ati pe awon kan n gbiyanju ni.

Olanrewaju Adedoyin lo soro yi lojo Aiku Sande to koja, iyen ojo ketadinlogun osu kewaa ti a wa yi lakoko to n b'AWIKONKO soro nibi ayeye kan ti won ti fun lami eye, awoodu gege bi akikanju lori eto aabo emi ati dukia awon araalu.

Eto ayeye naa ti ajo Flashlight Entertainment sagbateru e, labe Aare Ogbeni Wole Otuyelu (Don't Wallexy) to tun je Oludasile e lo waye lose to koja niluu Abeokuta, eyi ti won sori ayeye naa ni Ogun State Heroes of Change, iyen ni pe awon akoni to ti yi itan ipinle Ogun pada si rere.

Adedoyin so pe bo tile je pe oun ni oga ati adari egbe VGN kaakiri ipinle Ogun, sibe Olorun nikan loun le pe gege bi olori alaabo nitori pe lati atitikose nise Fijilante ti bere, to si je pe Olorun naa lo da a sile.

O ni oun ko ronu wi pe oun yoo gba ami eye naa nitori pe ise ilu lawon n se, toun ko si bebe fun un, sugbon to je pe o da a keeyan maa moriri awon to ba n ko ipa to da a lawujo.

Nigba to n soro lori awon aseyori tegbe naa ti se lodun yi, paapaa nipinle Ogun, Adedoyin so pe oun ko le iroyin awon aseyori naa tan, sugbon awon araalu lo le fenuso nipa ise takun-takun tegbe VGN awon ti se.

O tesiwaju pe yato si akitiyan tawon n se lori egbe naa lati le je nijoba apapo orileede lo egbe naa dofin, aimoye awon ipa alaranbara lawon ti ko laarin, tawon si ti mu awon odaran repete tawon araalu atawon oniroyin naa si le jeri sii.

Nigba to n fokan awon araalu bale, Komanda naa so pe eto aabo to peye lawon ti seto e sile fawon araalu nitori pe kaakiri ipinle Ogun lawon ti ko awon omo egbe won si lati daabo bo emi ati dukia won lakoko ati leyin odun to wole de yi.

Lakotan, Olanrewaju gbawon araalu lamoran wi pe kawon naa rii daju pe won jinna si iwa odaran, ki won si ma se bo enu won nigba ti won ba kefiri odaran lagbegbe won.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI