Egbon ataburo to n fipa bawon obinrin sun so pe oro awon kii soju lasan - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, January 9, 2018

Egbon ataburo to n fipa bawon obinrin sun so pe oro awon kii soju lasan

Se won lomo iya meji kii rewele ni, sugbon oro Nkoenye Jibunor ati Paul Jibunor ti yato gedengbe nitori ti won so pe won ko nise meji ju ki won maa fipa bawon obinrin sun kaakiri igboro lo, ti won si tun n lo anfaani e lati maa jawon eeyan lole.

Gege bi iroyin to te AWIKONKO lowo se so, a gbo pe ojo kokanlelogbon osu kejila odun taa sese lo tan yi la gbo pe asiri won tu sawon olopaa ipinle Ogun lowo nigba ti won ni odomobinrin kan, Ijeoma ti won fipa ba sun lojo kokandinlogbon osu naa loo foro won to awon olopaa leti, tawon yen naa ko si foro naa sere kinwon to gbe igbese.

Nkoenye ti won lomo odun mejidinlogbon (28) ni ati aburo Paul ti won lomo odun metalelogun (23) loun ati eni keta won ti won niyen ti na papa bora la gbo pe won maa n lo moto kan ti won pe ni Uber lati maa fi bays awon omobinrin je kaakiri.

A gbo pe ni se ni won n lo moto naa bi moto ti won fi n ko ero, sugbon to je pe ode obinrin ti won maa ba lo po, ti won si tun maa ja lole ni won fi n se.

Ohun ta a gbo ni pe agbegbe ojubo Fela to wa ni Oregun nipinle Eko ni Ijeoma ti dawon duro pe oun n lo si agbegbe Ojodu Abiodun, ti won si jo duna dura.

Iyalenu lo je fun Ijeoma nigba to rii pe won ya wo koro kan ki won too debi to n lo, to si beere pe nibo ni won n gbe oun lo, ti ko seni to da a lohun, nibe lo ti bere sii fura, sugbon ti ko mo nkan to le se.

AWIKONKO gbo pe bi won se de iwaju ile akoku kan ti won ti maa n sise ibi won ni won ba a fipa wo Ijeoma bo sile.ninu moto ti won si woo wole ki won too fipa bo aso e, ti won si bere sii gba kini abe won mon on labe.

Awon meteeta la gbo pe won mu nnkan labe Ijeoma, ti won si tun jaa lole awon eru to.ko sinu baagi to gbe dani ko too di pe won salo.

Lesekese la gbo pe Ijeoma ti gba tesan olopaa ekun Ojodu Abiodun lo lati loo fejo sun. Nigba tasiri won maa pada tu, Ijeoma lo tun kefiri won ladugbo Adebayo ni Ojodu kan naa, to si sare tawon olopaa lolobo wi pe oun ti rii won.

Ka ni awon olopaa lo.iseju kan si kinwon too gbera ni, o seese ko je pe awon meteeta ninwon maa salo, sugbon ti won pada ri meji mu lara won.

Ohun ta a gbo ni pe bi won se mu won tan, lawon eeyan bere sii yoju wi pe odaran paraku ni won nitori tawon mon won, sugbon tawon ko le foro won to olopaa lowo nitori ti won maa n dunkoko pe awon yoo pawon ni bi won ba so.

Nigba tawon mejeeji n soro ni won je ko ye awon olopaa wi pe oro awon kii soju lasan, o see se ko lowo aye ninu sugbon tawon ko mo ona min in lati maa ri owo.

Awon mejeeji ni won jewo pe o ti le lodun meji tawon ti n sise naa, tawon ko si.le soniye obinrin tawon ti fipa ba sun, tawon si tun ti ja lole.

Nigba to n jeri sii, Abimbola Oyeyemi to je agbenuso fawon olopaa so pe bo tile je pe iwadii sinn lo lati mu enikan toku won to salo, sibe orisirisi eru ti won ti fipa gba bii seeni, aago owo ati foonu ni won ri gba lowo won.

O ni Komisana won ti pase pe kawon olopaa to n ri soro awonnodaran,iyen SCIID tesiwaju ninu iwadii lati rii pe won mu eni to salo naa, ki won si foju won bale ejo lai pe.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI