"E se mi jeje,
E darijimi, ise esu ni" loro ebe to n tenu Arabinrin eni odun
mejidinlogbon (28), Anuoluwapo Josua jade lojo Eti Fraide to gbeyin odun 2017
ni Soosi Ridiimu ti Pasito Adeboye to wa ni Mowe, nipinle Ogun nigba towo awon
agbofinro te e, tasiri e si tu sita wi pe o ji omolomo tojo ori e ko ju odun
meta lo, iyen Akamaka Patience Francis gbe.
Ohun ta a gbo ni pe
ninu osu keje odun to sese koja lo yi la gbo pe Anuoluwapo ti ji Patience gbe,
lakoko ti won n se ipade olosoosu ti won ma n se lojo Fraide akoko ni gbogbo
osu, iyen Holy Ghost Congress nibi ti gbogbo omo ijo Baba Adeboye kaakiri
agbaye ti ma n peju pese sibe lati gbadura.
Gege bi iroyin to te
AWIKONKO lowo se so, won ni kii se pe Anuoluwapo deede pinu lati ji omo naa
gbe, sugbon nitori to ti paro fun okunrin kan to n fe pe oun ti loyun, ko si le
maa ri owo gba lowo e ni nkan bi odun meji seyin ko too salo siluu Oke Oya lati
so pe oun fe e lo bimo naa sibe.
Nigba to maa pada
de, ni okunrin naa so fun un pe nibo ni omo oun wa, oun fee foju kan, lo ba
bere sii pa orisirisi iro fun un wipe o si wa loke oya, sugbon nigba tiyrn so o
dija mo on lowo, lo ba ni koun loo gbe e wa ni Nassarawa to wa lai mo pe
omolomo lo fe e lo ji gbe.
AWIKONKO gbo pe
nigba to rii pe gbogbo ogbon arekereke lati ri omo kan ji gbe lo ja si pabo, lo
je ko gba soosi Ridiimu lo, to si lo sibi ti won n ko awon omo kekeeke si, ko
too gbe Patience salo.
Ohun ta a gbo ni pe
nigba to gbe omo naa dele, lo ba fun loruko min in, Funmilayo, sugbon gbogbo bi
won se n ba omo naa so ede Yoruba ti ko gbo, ni ko da won lohun, nitori ta a
gbo pe Ibo lawon obi e.
A gbo pe gbogbo bi
awon obi Patience se gbiyanju lati ri omo won pada lo ja si pabo, tonsi mu ki
won gba odo awon olopaa lo lati loo foro naa to won leti, tawon naa si n gbe
igbese latigba naa.
Nigba tasiri
Anuoluwapo maa tu, ohun ta a gbo ni pe obinrin kan ni Anuoluwapo gbe Patience
fun, tiyen si gbe e lo si ipade awon omode ni Ridiimu naa, enikan to da omo naa
mo lo sare loo ta awon olopaa lolobo.
Lesekese la gbo pe
awon olopaa ti yoju sibe ti won si rii pe looto ni. Eyi lo fa a ti won fi duro
ti omo naa pe awon fee mo eni to muu wa, bi won se n pari ipade naa ni obinrin
yi mu, to si fe maa muu lo, ko to o di pe won rowo to, ti won si beere lowo e
pe nibo lo ti ri omo.
A gbo pe bo tile je
pe nkan to.koko n so ni pe omo oun ni, sugbon nigba to rii pe won ko mu oro naa
ni kekere, ti won si so pe omo ti won ji gbe ni, lo ba ni ki won se oun jeje,
omo ore oun kan ni.
Lesekese ti
Anuoluwapo ti foju kan aso olopaa la gbo pe o ti fee na papa bora, sugbon ti
won pada dana duro, to si bere sii bebe pe ki won se oun jeje, ati pe ojukokoro
lo sun oun de be, nitori toun ti paro foko toun n fe wi pe oun ti bimo fun,
nigba toun ko fe ko bo koun lowo.
Ni bayii, Ahmed
Iliyasu to je Komisana olopaa ipinle Ogun ti so pe awon ko bii foju aanu wo
Anuoluwapo gege bi oruko e, nitori se lawon yoo foju e bale ejo.
O wa kilo fawon
odaran atawon to sese fee bere iwa odaran wi pe ki won loo so ewe agbeje mowo
nitori toun ko bii gbawon laaye lodun 2018 yi.
No comments:
Post a Comment