Idi ti mi o fi da si egbe PFC tele - Pasuma - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, January 31, 2018

Idi ti mi o fi da si egbe PFC tele - Pasuma


Gbajumo olorin Fuji nni, Alaaji Wasiu Alabi Odetola tawon ololufe e mo si Pasuma ti so idi ti ko fi da si egbe awon ololufe e, iyen egbe Pasuma Fans Club (PFC) latigba ti won ti da a sile lodun 1996. O ni ko si nkan meji toun ko fi koko da si fun bii odun mokanlelogun (21) ti won ti bere e bi ko se pe egbe naa ko ye oun si, bo tile je pe oruko oun ni won n lo.

Pasuma atawon oloye egbe
Pasumo soro yi nibi ayeye ibura fawon oloye egbe naa tuntun ti won sese dibo yan, nibi ti won tun ti lo anfaani e lati sayeye ojoobi aadota (50) odun fun un ninu gbagede ayeye Blue Roof to wa ninu agba ileese Telifisan LTV8 ati Radio Lagos/Eko FM, Ikeja niluu Eko.

O so pe bo tile je pe latigba ti won ti da a sile ni won ti n be oun pe koun darapo mo won, sugbon toun so pe ki won ma a ba a lo, nitori pe ko si nkan to ka noun nipa oro egbe naa, toun ko si da sii.

Ilumooka olorin Fuji to tun ti darapo mo awon olorin taka-sufe hiphop naa so pe nigba ti wahala bere ninu egbe naa, ti won fi n to oun leti, oun ko da si nitori pe ko si nkan to kan oun nibe nitori pe oun ko si lara won, ati pe nigba tawon agbaagba ranse pe oun ti won si si oun leti wi pe boun ba so pe oun ko nii da sii, to si je pe oruko oun ni won fi n se egbe naa, ko nii da ki won lo anfaani egbe lati ba oruko oun je.

O ni iyalenu legbe naa n je foun nitori pe latigba toun ti n ri awon eeyan ti won n segbe, oun ko tii ri egbe ti won fi itara okan (passion) mu bii ti egbe PFC, to si tun je iwuri foun, nitori pe kaakiri agbaye ni won ti n se e.

Ninu oro e, o so pe “Lati ojo ti mo ti n rii wi pe won n se egbe, mi o tii ri egbe ti won mu ni okunkundun bi egbe Pasuma Fans Club yi ri. To ba ti dip e egbe ti di bee, o tun mo sip e egbe naa ti gbooro niyen. Ko ma le di ti ija, ko ma di ti egbe oni wahala lo je ki n da sii, to ri pe mi o kii fe e da si tele. Awon egbe ni won n tuko egbe funra won, Pasuma lo ni oruko, ti Pasuma ba ti da si, igba yen lo maa di wi pea won eeyan a bere sii soro pe nkan bayii ni ke e se, tawon kan maa so pe Pasuma lo ni ka se be e, oun lo n dari egbe e, oun lo n pase egbe e, mi o si fe e. idi ti mi o fi da si niyen.

“Ni nnkan bii osu mefa seyin, ti oga wa, Saheed Imagination ti di Aare egbe PFC lo ti di pe awon nkan ti ko ye ko maa sele ninu egbe fe maa sele, awon eeyan lo pe mi si akiyesi wi pe won ti fe e ba oruko mi je, bo tile je pe awon to n segbe naa feran mi looto, sugbon oruko mi ni won n lo, to si ti won si ti fe e ba a je.

“Won ni ki n gbiyanju agbara mi lati yanju wahala to n sele ninu egbe. Igba ti Oga wa Eleyele ti won di Aare, awon eeyan lo dibo wi pe oun lawon fe e nitori pea won kan lo wa nibe tele nigba yen. Nigba ti asiko won tan, ti won tun gbe foomu jade wi pe won fe e ta a, awon bii meta lo jade lati ra a. Leyin ifigagbaga laarin Ogbeni Adeola ati Ogbeni Eleyele, ni Ogbeni Adeola wole, ti Eleyele ko si ronu wi pe koun fegbe sile nigba toun ko ti wole.

Pasuma wa a lo anfaani ayeye naa lati fi dupe lowo awon omo egbe naa to wa nibe paapaa kaakiri agbaye fun ife ti won ni sii lati wa ninu egbe PFC, to si gbadura pe inu won yoo maa dun titi lai. Bee lo seleri wi pe oun yoo maa se awon iranlowo to ba fun egbe naa.

Godfather
Nigba to n soro, Oludasile egbe Pasuma Fans Club, Alaaji Semiu Afolabi tawon eeyan tun n pe ni GodFather so pe idunnu nla lo je foun lati je oludasile egbe PFC nitori pe egbe naa ti koja oju tawon eeyan fi n wo o, nitori pe awon omo egbe naa kaakiri agbaye ti le ni milionu mewaa, ti kii se pe orileede Naijiria nikan ni won ti n segbe naa.

Godfather nigba to n sapejuwa Alaaji Pasuma, o ni Pasuma da bi Anobi tawon eeyan n tele, nitori pe Olorun dee de seda e lona ara, to si ti pari ise sii lara. Bee lo tun fi Pasuwe we Aare Ona Kakanfo ile Yoruba, Oloye Gani Adams nitori pe eda to ba ni afojusun lo maa n de ile ileri.

Nigba to n soro lori idi ti won tun fi se ayeye ojo ibi fun Pasuma, Godfather je ki di mi mo pe awon rii gege bi anfaani lati bu ola fun eni ti aye n gba ti e nidi ise orin Fuji naa, bo tile je pe ojo ketadinlogbon osu kokanla odun to koja ni won ti sayeye naa ganagan

Imagination
Aare egbe PFC, Ogbeni Adewunmi Olalekan Saheed tawon eeyan tun n pe ni Imagination nigba toun naa n sapejuwe Alaaji Wasiu Alabi, o ni “Pasuma je eda kan to nife awon eeyan bi ara e, eni to ko eeyan mora ni, to sit un ni irele.

Imagination so pe oun nigbagbo pe ni nkan bi odun marun sasiko yi, egbe PFC maa ni ileese nla to ma maa gba awon eeyan si ise, ti kaadi idanimo egbe si maa wa lowo won. O legbe naa maa bere sii mu awon eeyan lo si oke okun gege bi omo egbe, bo tile je pe egbe naa ti n ran awon eeyan lo si Meka ati Imura, ti won si ti n ta ile fawon omo egbe lowo pooku.

Bashorun
Akowe agba fegbe PFC, Ogbeni Olatunji Basorun so pe oun kii se egbe, sugbon nigba toun wo ogo egbe, toun ri ti egbe PFC lo je koun darapo mo awon to n se e losu mejila odun 2014.

O ni bo tile je pe owo apo ara won lawon fi n se egbe naa, sugbon awon anfaani to po jaburata loun ti ri nibe, lara won lawon toun ko lero wi pe oun le ba soro laye, toun bawon pade, tawon sit un jo dapara, jiroro. Basorun so pe egbe naa maa n mu awon eeyan mo awon eeyan  nla-nla lawujo, ti won a si tete se aseyori laye won. Bee lo so pe opo awon eeyan ni won ti lo anfaani egbe naa lati ri ise.

Gomina egbe PFC nipinle Eko, Alaaji Babatunde Olaniyan nigba to n soro lori Pataki egbe naa, o so pe egbe naa mu ife, isokan lokunkundun, tawon sit un n lo anfaani e lati ran ara won lowo ni gbogbo ona, tawon si tun ti bawon odo alainise wa ise.

Fasiu Idiagbon to je Gomina egbe PFC niluu Abuja so pe oun tii figba kan kabamo wi pe oun darapo mo egbe naa, toun ko si nii ni lero wi pe oun yoo fi sile titi lai nitori pe lara awon anfaani toun ti je ninu egbe yi nit awon eeyan jankan-jankan toun ti mo latara egbe naa. O ni ekun (zone) meta loun ba nigba toun di Gomina, sugbon tie kun naa ti di mokanla bayii, tawon si ti ni ju omo egbe to le ni aadota (50) lo.

Gomina egbe PFC nipinle Edo, Sunday Ayodele opo awon omo ipinle Edo ni won n gbiyanju lati je ki Alaaji Pasuma wa sipinle naa lati wa a korin fun won nitori pe ife ti won ni sii ko se e fenuso tan. Bee lo rawo ebe sawon agbaagba egbe naa lati je ki afojusun won le wa si imuse lai pe.

Arabinrin Rofiat Ayoola Adunni to je Gomina egbe naa nipinle Taraba nigba to n soro nipa Alaaji Pasuma, o so pe toun ba menuba oro Pasuma, oun ko nii so o tan lojo kan soso nitori pe akanda eeyan ti Olorun da fawon ololufe e ni. O ni iwuri nla lo je foun lati je Gomina obinrin kan soso fegbe PFC tawon eeyan n gba ti e.

Abass Olaniyi to je Gomina egbe naa nipinle Taraba je ko di mi mo awon omo ipinle naa feran orin Pasuma gidi gan, to si n je idunnu foun lati je okan lara awon gomina egbe naa.

Okan Pataki lara awon Aafa to n gbadura fun Pasuma, Alaaji Mustapha Abiodun so pe lati kekere lawon ti bere sii se ore, toun ko sit ii kabamo lati mo Alaaji Wasiu Alabi. O ni lati ojo ti Pasuma ko tii lowo lowo lo ti n saanu fawon alaini, toun si n ko eko lara e.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI