Nnkan To Le Mu Ki N Dariji Amosun – Segun Sowunmi - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, January 31, 2018

Nnkan To Le Mu Ki N Dariji Amosun – Segun Sowunmi




…Asiko ti to fun egbe oselu APC lati fijoba sile

Ogbeni Segun Sowunmi to n foju sona lati dije dupo omo ile igbimo asofin agba niluu Abuja (House of Representative) ti so pe nkan kan soso to le mu koun dariji Gomina ipinle Ogun, Ibikunle Amosun pelu awon ise akanse to loun n se nipinle Ogun, to je pe ilu Abeokuta to ti wa nikan lo n se e si ni pe to ba le je ki oko baluu (Aeroplane) bale sipinle naa. 


Segun Sowunmi
Segun Sowunmi so pe bo tile je pe oun ko ba Gomina Amosun ja, nitori pe arakunrin oun ni, tawon si jo ni itan papo, sugbon oun ko le la oju oun sile lati ma so awon ibi to ku si gege bawon se je omo ilu kan naa.

O soro yi lakoko to n gbawon oniroyin ero ayelujara, iyen National Association of Nigerian Bloggers (NANB) lalejo lai pe yi niluu Abeokuta, nibi to ti so pe ijoba adanikan se ni Amosun n se nipinle Ogun, ti ko si fawon komisana atawon amugbalegbe e lenu oro.

Sowunmi so pe ko ye ki gomina to loun feran awon araalu e maa se awon akanse ise silu to ti wa nikan, bi ko se pe ko je ki gbogbo awon ipinle e jegbadun e, ki won si je mudun-mudun ijoba awa-ara-wa.

O so siwaju pe bi won ba wo awon ise ti Gomina Amosun loun n se nipinle e, won yoo rii pe ilu Abeokuta to je olu ilu ipinle Ogun tokunrin naa ti wa lo n sise ju si, ti ko si ronu idagbasoke sawon ilu to ku, o ni ko bojumu to.

Ninu oro e, o so pe “Nipa idagbasoke igbalode ati tit un awon ona se lona igbalode niluu Abeokuta ti mo ti wa, maa dupe lowo Gomina Amosun, sugbon lesekese ni maa beere lowo e pe se o ti de awon agbegbe to ku nipinle Ogun bii; Ado-Odo Ota, Igbesa, Agbara/Lusada, Mowe/Ibafo, Alagbole/Ifo, Akute/Ajuwon, sugbon to ba so pe rara, maa gba a niyanju wi pe ko lo sibe lati lo wo nkan to n sele.

“To ba so pe oun ti de be, ma a beere lowo e pe se lero okan e, bi won se n sejoba lo se n se yen, to ba so pe beeni, maa ni ko ye ko ri bee, bi won se n sejoba ko niyen.

“Ma a beere lowo e pe yatro si afara oloke (bridge) atawon opopona to ja geere, ki lo tun ro pe ipinle Ogun nilo gege bi idagbasoke, to ba so pe ko sii, ma a so fun un pe kii se be. Ma a beere lowo e pe se awon ile ti ko wulo to pe nileewe igbalode (Model School) to ko kaakiri, ti ko wulo lo fe e so pe o je idagbasoke leka eto eko, to ba so pe beeni, maa so fun un pe ko ye ko ri bee, nise lo ye ko se awon atunto liana eko, ko si tun awon ileewe to ti fe e wo tan ko. Eto ilera naa pelu awon nkan ti mo maa menuba wi pe ko loo satunse le lori.

“Ko seni to le soro ninu isejoba Amosun, o maa soro ki e to le gboro lenu enikeni ninu awon komisana e yato si bi won ba fe e paro. Ko ye ko ri be e. Ma a dupe lowo e nitori pe ko je awon osise ijoba lowo osu, ti ko sit un si wahala laarin oun atawon Oba nipinle Ogun.

Sowunmi
“Mo fe ki e mo daju wi pe ijoba e ti fe e tan, awon omo ipinle Ogun si ti fun un ni anfaani lati sin won lemeeji. Nkan kan soso to n kan mi lominu ni eni ti yoo gbajoba lowo Amosun, nitori pe se ni aya mi n ja ki eni naa ma tele liana ti Amosun fi sile. Bi omo Yewa ba wole gege bi won se n fe, ko ma lo je pe ile Yewa loun naa maa doju ko lati fi gbesan. Bee lominu n kan mi lori gbese ti eni ti yoo gbajoba lowo e maa ba nile. Nitori wi pe awon eeyan ko soro, ko tunmo si wi pe won ko ri, ko tunmo si wi pe won ko mo nkan to n lo.

“Mo lo si Badagry lodun to koja, mo si gba ona Agbara lo, nigba ti mo de agbegbe yen, ti mo ri awon ileese nla-nla nibe pelu awon ona to gba ibe koja, aanu se mi, latari iya ti won n je lori aini ona to ja geere ti mo le rin lai fese ko. Wi pe ona kan je ijoba apapo ko tunmo si wi pe ijoba ipinle ko le sise de be lati je kawon eeyan jegbadun mudun-mudun ijoba awa-ara-wa.

“Nkan kan soso le mu ki n dariji Gomina Amosun ni to ba le je ki oko baluu wo ipinle Ogun gege bo se so pe oun maa se koun to o lo. Ti eyi ba ti see se, ko soro mo. Eeyan mi ni, kii se ota mi, ati jo ni itan papo ri nigba kan. Nkan ti mo n gbadura si Olorun nip e ko fun wa lawon adari to nironu to dara lati gbajoba bi awon adari bii Oloye Olusegun Osoba, Gbenga Daniel ati Amosun funra e.”

Nigba to n soro lori isejoba egbe oselu All Progressive Congress (APC) lorileede Naijiria, paapaa ijoba Aare Muhammadu Buhari, Segun Sowunmi so pe asiko ti to fawon omo orileede yi lati loo gba kaadi idibo alalope (Permanent Voter Card), PVC won ki asiko idibo to o de, nitori pe asiko lati gbajoba lowo won ti to.

O sapejuwe ijoba APC gege bi ijoba to ti kuna latari awon ileri manigbagbe ti won se lasiko ipolongo idibo odun 2015, wi pe awon yoo so owo dola kan di naira kan, tawon yoo si maa fawon odo ti won ko nise lowo legberun marun-marun losoosu, ti won ko sir ii se, paapaa bi won tun se seleri wi pe awon yoo ja owo epo bentiroolu wale lati naira metadinlogorun (97) naira si ogoji naira, to je pe pabo lo ja si.

Bakan naa lo bu enu ate lu Asiwaju Bola Ahmed Tinubu latari bo se lewaju awon omo ile Oduduwa lo sabe awon Fulani to n pawon omo orileede yi nipakupa ti Aare Buhari ko si so nkankan lori e.

O ni bi inu Tinubu ba dun sib awon Fulani se n pawon omo leyin Kristi atawon ti kii se eya ti Buhari ti jade wa, dajudaju, okunrin naa ti kuna lati dale awon omo Oloogbe Obafemi Awolowo.

Bee lo gbosuba fun Oloye Olusegun Obasanjo fun leta to ko lati fi tako ijoba Aare Buhari latari bo se n sejoba aibikita emi ati dukia, paapaa alaafia awon omo orileede yi. O ni bi Obasanjo ba le ni igboya lati ko iru leta naa, ko si nkan to di awon bii Abdulsalam, Sagari, Sonekan, Babangida, paapaa Tinubu lowo lati dide soro, tabi ko iru leta be e.

O ni kii se pe bi won ba ko leta naa, Aare Buhari yoo fipo sile wi pe oun ko se e mo, sugbon lati mo awon ibi to ku si, ko si tun ero ara e pa lori bo se n sejoba, atawon to yan sijoba e.

NIgba to n soro lori ipinu e lati dije dupo asojusofin lati ekun Abeokuta South, o so pe idagbasoke ilu oun lo je oun logun, toun si rii pe awon ti won ti n ran lo siluu Abuja lati soju won, kii se nkan to ye ki won se.

O ni orisirisi ona igbalode loun ni lati mu idagbasoke wo ipinle Ogun, paapaa nijoba ibile apapo toun ti fe e jade, lara e ni ri ro awon odo lagbara lati da duro, lai duro de enikeni lati jeun.

Sowunmi so pe kii se pe ri ra okada lo le mu idagbasoke wo ilu, nitori bi asojusofin ba so pe oun n ra okada tabi keke maruwa fawon eeyan, a a je pe se niru eni bee fe e so gbogbo eeyan di olokada laarin ilu niyen.

Bee lo rawo ebe sawon araalu lati ran oun lo soju won niluu Abuja tasiko ba to, nitori pe oun ri ara oun gege bi eni to kun oju osuwon lati soju won nilu Abuja.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI