Mo si maa dije dupo gomina nipinle Ogun - Paseda - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, January 21, 2018

Mo si maa dije dupo gomina nipinle Ogun - Paseda

Bo tile je pe nnkan tawon kan so ni pe awon ko tii mo boya oludije fun ipo gomina labe egbe oselu Unity Party of Nigeria (UPN), Otunba Olarotimi Paseda  yoo tun jade dupo mo lodun 2019 nitori awon ko mo erongba e.

Sugbon okunrin naa loun ti si pe oun ti pinnu lati jade dupo gomina nipinle Ogun lodun 2019, ati pe ko seni to le so pe koun ma jade dije nigba tasiko ba to.

Paseda soro naa niluu Ijebu lasiko to n bawon igbimo Baale Omu, iyen Omi Council of Baales pelu awon igbimo ipolongo e (Paseda Supporters Network) sepade l'Ojobo Tosde ose to koja yi.

O ni aheso lasan ti ko lese nile ni wi pe oun ko ni ipinu lati dupo gomina mo nitori toun ko soro nipa e, ati pe oun si n sepade pelu awon alagbara kan nipinle naa, toun gbagbo pe won yoo satileyin foun nigba ti asiko ba to.

Bee lo sapejuwe aheso kan to so pe awon eeyan tun n gbe kaakiri nipa oun wi pe ipinu lati dupo omo ile igbimo asofin, House of Representative gege bi oro awada ti ko se e gbagbo.

Omoba Paseda tesiwaju pe ipinu lati gba ipo akoko (Gomina) lodun 2019 ko se e duna-dura pelu enikeni, nitori pe abajade esi awon eleto idibo, iyen INEC nipa egbe oselu loun n duro de, ko to o di pe oun bere sii soro oselu.

Bee lo so pe aheso naa ni lati si awon eeyan oun lokan, ati lati mu ipinya ba won ni won gbe kiri, to si ro won pe ki won ma se gba oro naa gbo rara.

Ninu oro e, o so pe "Ipinu mi lati dupo gomina si wa digbi, ti ko si ye, ki enikeni ma si lero wi pe mo ti gbe ipinu naa ti segbe kan. O je nkan to n pani lerin ati pe awon alatako mi ni won wa nidi oro aheso naa.

"Mi o ni nkan kan se pelu ipo omo ile igbimo asofin tabi ipo seneto, awon to n gbe oro naa kiri ti ri ipinu mi lati dupo gomina naa gege bi iberu fun won.

"Mo mo pe won ti n wo ilu Ijebu wa ti won si ti de pelu owo wa ti won ji ko niluu Abuja gege bi won se maa n se. E gba owo won ki e si tele ife okan yin nitori asiko ikore owo la wa yi."

Bee lo gbawon to ni ipinu lati jade dupo pe ki won yee sere egele, paapaa lati maa gbe awon iroyin aheso ti ko lese nile kaakiri, ati pe ki won rii daju pe owo awon ti te tikeeti lati dije dupo ko to o di pe won bere oro oselu.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI