Ph.D: GNI gboriyin fun Obasanjo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, January 21, 2018

Ph.D: GNI gboriyin fun Obasanjo

Bee lo gbawon odo lamoran


Adije sipo gomina ipinle Ogun leemeji otooto labe asia egbe oselu Peoples Party of Nigeria (PPN) ati Peoples Democratic Party (PDP), Omoba Gboyega Nasiru Isiaka ti gbe osuba kare fun Aare teleri lorileede yii, Oloye Dokita Olusegun Okikiola Obasanjo fun ti oye Dokita to sese gba leyin to pari asekagba nile iwe giga National Open University (NOU).

Omoba Isiaka sapejuwe Baba Obasanjo gege bi adari ti ko lafiwe nile adulawo (Afrika), ati pe imo iwe ati oye to sese gba naa je ko tayo laarin awon akikanju nile Afrika.

O tesiwaju ko wopo lati ri eeyan tojo ori e se deede ti Oloye Obasanjo pelu ipo e lawujo lati jowo ara e sile pelu irele lati keko de ipele naa ko si gba oye yi.

O wa gbawon odo orileede Naijiria lamoran wi pe ki won wo Dokita Olusegun Obasanjo gege awokose ati adari to se e fokan tan, nitori pe igbesi aye e je eyi to wu ni lori, teeyan si gbodo maa mulo.

Ninu oro, GNI so pe "Iran awa odo yi gbodo maa ri awon eeyan bi Oloye Obasanjo gege bi eni amuyangan, eni ti itan igbesi aye e dabi iwe ti a si nigba gbogbo.

"Gege bi agbalagba pelu ojo ori e, to si n gbiyanju lati ni imo iwe siwaju sii, o tun mo si wi pe o ti atejise ranse si wa pe ojo ori kii se babara, ko si je nkan to le so pe keeyan ma lo sile eko lati ko eko siwaju sii

"Baba n so fun wa pelu aseyori e yi pe a gbodo mu oro eko lokunkundun lorileede Naijiria, paapaa nipinle Ogun nibi ti Baba Obasanjo ti wa. Nitori e lo se je pe  eto idagbasoke awon eeyan lati le da duro funra won ni nkan ti mo maa sise le lori ti n ba de ijoba lodun 2019, pelu ife Olorun."

O wa gbadura fun Dokita tutntun naa, Oloye Obasanjo wi pe ki Olorun Olodumare fun un ni ilera to pe ye lati le maa tesiwaju gege bi ipo baba lorileede Naijiria, Afrika ati lagbaye.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI