Owo te Noah to n se fayawo igbo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, January 9, 2018

Owo te Noah to n se fayawo igbo


Nise lenu ya opo awon eeyan to ri aworan baagi igbo to fi merinla le ni ogorun (114) eyi ti won so pe Okunrin kan Noah Olaore ti won ni ko nise meji ju ise fayawo igbo lo ko wole sorileede yi lati orileede Olominira Benin.

Gege ba a se gbo, ojo kokandinlogun osu kejila odun ta sese lo tan yi ni won so pe asiri Noah tu sawon olopaa SARS lowo ladojuko papa isere MKO to wa ni Kuto niluu Abeokuta.

A gbo pe nise ni Noah fi moto se fayawo orisirisi baagi igbo wole lati Kutonu, to si je pe nise lo yo boro mo awon kositoomu lowo nigba ti won da a duro.

AWIKONKO gbo pe bi won se gbiyanju lati le Noah mu to, pabo lo ja si, eyi lo fa a ti won fi ranse sawon olopaa SARS lati foro naa to won leti.

A gbo pe awon olopaa SARS ti loo duro de Noah ladojuko papa isere MKO naa nitori ti gbo pe ona to fe e gba niyen, lati maa lo si Igbo-Ora.

Lara awon to foro naa to wa leti je ko ye wa pe kii se Noah nikan ni won mu lojo naa, sugbon teni ti won jo wa ninu moto naa ri aaye lati na papa bora ni ti e.

Nigba ti won bere ise iwadii, ti won bere sii foro wa Noah lenuwo, lo ba jewo fun won pe kii soun nikan loun n sise naa, ati pe o nibi tawon maa n ko awon igbo naa si.

Eyi lo fa a ti won fi teko leti loo silu Igbo Ora nipinle Oyo nibi tawon toku e wa, ti won si tun n ko igbo pamo si.

Iyalenu ni won loo je nigba ti won de be ti won ba baagi igbo repete, nigba ti won si ka a tan pelu eyi ti won tun sese gba lowo e, ni won rii pe ogorun kan ati merinla ni apo igbo naa je.

Bo tile je pe oun ta a gbo ni pe awon ti won jo n sise ti na papa bora lesekese ti won gbo pe awon SARS ti n bo.

Ni bayii, Komisana olopaa, Ahmed Iliyasu ti pase pe ki iwadii tubo tesiwaju paapaa lati mu awon toku to salo naa lati le foju won bale ejo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI