Tirela te Saheed lori okada n’Ilogbo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, January 4, 2018

Tirela te Saheed lori okada n’Ilogbo

"Olorun ma je ka rin lojo tebi n pa ona" ni adura to ye kawon eeyan tete maa se "amin" si nigba ti won ba feti gbo o. Nise lawon eeyan to wa lagbegbe Iyana Ilogbo nijoba ibile Ifo kawo sori, ti won n pariwo ikunle abiyamo nigba ti tirela te okunrin kan ti won poruko e ni Saheed pa.

Gege b'AWIKONKO se gbo, ni nnkan bi aago mejo aabo ale ojo Tosde ose to lo lohun nisele buruku naa waye lakoko ti won so pe Saheed fee gun okada, sugbon ti ese e sesi yo.

Eni to gbe iroyin naa s'AWIKONKO leti so pe ibise ni Saheed ti m bo lale ojo naa, to si n lo sile, okada to ma a gbe dele lo so pe o fee gun lojo naa ki ori to tako o.

O ni agbegbe Arigbajo ni tirela naa ti n bo, sugbon nitori ona Iyana Ilogbo naa ti ko da a, lo fa a ti ese Saheed fi yo lori okada naa, ko to o di pe aso e ko irin to wa lara tirela naa.

AWIKONKO gbo pe bi aso Saheed se ko irin lo fa a sabe taya, to si te e lori pa, lesekese lo si ti dagbere faye nitori pe se ni opolo e fo jade lesekese.

Awon tisele naa soju won la gbo pe won pariwo le awako tirela naa ti won so pe bo se bo sile lo ti na papa bora pe ko duro, nitori pe o ti paayan.

Ohun ta a gbo ni pe awon eeyan ni won ranse sawon olopaa lati foro naa to won leti ko too di pe won gboku Saheed lo si  mosuari osibitu ijoba, iyen jenera to wa ni Ifo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI