Lojo odun keresimesi; awon olopaa pa Mungo Park Ogbologbo adigunjale danu - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, January 4, 2018

Lojo odun keresimesi; awon olopaa pa Mungo Park Ogbologbo adigunjale danu

Nise ni idunnu subu lu ayo awon araalu Ogbere lojo aje Monde ose to koja, iyen lojo odun keresimesi nigba ti owo olopaa ipinle Ogun te ogbologbo adigunjale ti won lo ti n yo awon araalu lenu lati ojo pipe wa, to si je pe lojo naa lo ta teru nipa.

Bo tile je pe iroyin ti jade sita tele lojo kerinla osu kesan wi pe won ti pa okunrin naa ti won pe ni Mungo Park leyin ti won mu awon meji kan, sugbon tawon meji naa, Wasiu Ganiyu ati Azeez Komolafe pada so f’AWIKONKO pe kii se Mungo Park ni won pa, gbakeji e ni, ati pe Park lo ko awon lo lojo naa nini tibon ti ba DPO olopaa ti ekun Ogbere, Ogbeni Adeyinka Akingbade, eni ti won lo si wa losibitu to ti n gba itoju titi di asiko yi.

Fawon to ba si ranti nipa isele naa daadaa, ojo ketala osu kesan odun yi ni Mungo Park atawon egbe e ti won jo n jale loo kolu oteeli kan taa foruko bo lasiri l’Ogbere, nibe ni won ti yinbo fun DPO Adeyinka, tawon olopaa to ku si salo, leyin wakati mefa ni won too ri awon kan mu, tawon to ku sin a papa bora.

Asiko naa la gbo pe Mungo Park ti salo sipinle Delta nibi to ti loo fori ara e pamo fawon olopaa, lai mo pe ojo iku oun naa yoo pada de, nitori tawon olopaa ko sinmi lori bi won se le rii mu.

AWIKONKO gbo pe opin ose to lo lohun ni won ni Mungo Park tun pada yoju lero wi pe won yoo ti gbagbe nipa oran toun ti da sile, sugbon nigba to maa yoju, Ijebu Ife lo de si lodo ore e kan, to sit un wa bawon eeyan sayeye odun keresimesi.

Ohun ta a gbo ni pe nigba to ma a di ojo Monde lo gba ile oti to wa ladugbo Itawade n’Ijebu Ife naa lo lati loo se faaji pelu awon eeyan e, nibe lawon kan ti tawon olopaa lolobo wi pe won ti rii, tawon olopaa naa si gbera lati loo mu, sugbon nigba tawon olopaa ma a fi de be, o ti kuro.

A gbo pe awon kan naa lo ta oun naa lolobo wi pe awon olopaa ti n bo lati waa mu, ko loo salo sile awon ebi iyawo lati loo fori pamo, ati pea won to n so naa lo tun so fawon olopaa wi pe ibe lo lo.

Ohun ta a tun gbo ni pe nigba ti won maa wa de be, to foju kana won olopaa lo ti yo ibon ilewo to n fi sapo kaakiri, to sib ere sii yin fun won, sugbon tawon olopaa fori won pamo lero wi pe ota ibon naa uyoo tete tan, sugbon nigba ti won rii pe ko mu oro naa ni kekere lo je kawon olopaa naa doju ibon ko o, tibon naa si ba a.

Lesekese la gbo pe o subu lule to si ku patapata, ko too di pe won gboku e lo si tesan nibi ti won ti lo fi han fawon eeyan wi pea won ti pa eni tawon ti n wa tipe, ti won sit un pada gbe e lo si mosuari ileewosan ijoba.

Nigba to n gba enu komisana olopaa Amhed Iliyasu soro, agbenuso fawon olopaa Abimbola Oyeyemi so pe bo tile je pea won sise takuntakun lati mu ogbologbo odaran naa, sibe inu oun dun wi pea won rowo to nigbeyin.

Abimbola je ko di mimo pe titi di asiko yi ni DPO olopaa naa si wa ni osibnitu to ti n gba itoju lowo, to si so pe ileese olopaa ko figba kan duro lati maa gbogun ti awon adigunjale. O tun je ko di mimo pe lara awon nkan tawon ri gba lowo Park ni ibon ilewo, ada ati moto Toyota Highlander to n lo peli nomba idanimo meji otooto pelu awon ogun abenugongo lorisirisi.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI