Won Ni Alaga Acomoran Atan-Ota n fi aye ni awon olokada lara nitori owo tikeeti - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, January 22, 2018

Won Ni Alaga Acomoran Atan-Ota n fi aye ni awon olokada lara nitori owo tikeeti

Ni Won Ba Ni Ki Amosun Gba Awon

Beeyan ba niluu Atan-Ota lose to koja yi, to ri bawon olokada se n fomije rawo ebe sijoba ipinle Ogun labe Gomina won, Ibikunle Amosun latari bi won se so pe alaga egbe Acomoran, Ogbeni Mukaila ti won tun n pe ni Basuka ko fokan won bale nitori bo se n fojoojumo fowo kun owo tikeeti okada ti won n gba.
Opo awon olokada agbegbe naa to b'AWIKONKO soro ni won so pe awon ko ona min in tawon tun le gba lati je ki isoro tawon n koju niluu Atan-Ota nijoba ibile Ado-Odo Ota di ohun igbagbe, bi ko se pe kawon tete rawo ebe si Gomina Amosun lati tete ba won da sii.

Ohun ta a gbo ni pe ni se ni okunrin alaga naa, iyen Basuka fi owo kun owo tikeeti okada won n ja, to si so o di egberun kan din ni ogorun (900) naira, eyi ti won so pe agbara won ko gbe, bo tile je pe irinwo (400) naira ni ijoba ipinle Ogun fowo si wi pe ki awon olokada maa ja tikeeti lojumo.

AWIKONKO gbo pe eedegbeta aabo (550) naira ni owo ti awon olokada Atan-Ota maa n ja tikeeti tele lojumo, sugbon nigba to di osu kinni in odun 2016 ni oro yi pada, ti won si so pe Basuka fowo kun owo naa, to so o di egberun kan din ni ogorun (900) naira.

Oro naa la gbo pe o di awuyewuye repete, tawon agbaagba ilu naa si ba won da si, ko to o di pe won ja owo naa wa sile si eedegberin (700) naira.

Iroyin to te AWIKONKO lowo je ko ye wa pe nkan to fa a ti won fi fowo kun owo tikeeti nigba naa ni pe, won so pe won fi owo Oba ilu naa atawon ijoye kun un.

A gbo pe nigba naa, adehun ti won pada yori oro naa si ni pe, o tun di eyin odun merin ki won tun to le ronu lati fowo kun owo tikeeti naa, ki onikaluku si maa ba ise won lo lai si idaduro, tawon olokada naa si gba bo tile je pe ko te won lerun.

Iwadii ti AWIKONKO se je ka mo pe lawon ilu bii Owode Yewa, Magboro, Idiroko, Ilaro, Agbara atawon ilu min in nipinle Ogun, ko si ilu ti won ti n ja tikeeti ni owo to to eedegberin (700) naira.

Owode Yewa - 500; Ilaro - 500; Idiroko - 450; Agbara/Lusada - 600; Abeokuta - 400. Eyi ni iye ti a gbo pe won n ja tikeeti lawon ilu won yii, ti ko si seni to le so pato bi won se n fowo kun owo naa pelu bi ijoba ipinle Ogun se pa a lase wi pe irinwo (400) naira ni ki won maa ja tikeeti lojumo.

Lara awon to b'AWIKONKO soro lose to koja yi je ko ye wa pe bi awon ba siro owo tikeeti tawon n ja tikeeti lojumo nipari osu, egberun mokanlelogun (21,000) naira  gbogbo e je.

Okunrin naa ta a foruko bo lasiri so pe, bo tile je pe igba igba din logun naira (180) lawon n ra jaala epo robi, iyen bentiroolu (petrol) ni ile epo, tawon ko si fowo kun owo tawon n gbe eeyan, sibe awon alaga Acomoran ko fi won lokan bale.

Okunrin naa tojo ori e ko tii ju odun mokanlelogbon (31) lo so pe alaga Acomoran yi, Basuka ti gba owo kan to pe ni Hackney Permit ati owo iwe ti won n le mo okada lowo won lodun meji seyin, tawon ko si ri nkan tawon san owo fun.

O ni apapin ni Basuka atawon eeyan e fi owo naa se. O je ko ye wa pe egberun kan aabo (1,500) naira lowo ti olokada kookan san lati fi gba Hackney Permit ati iwe alemokada (sticker), to si je pe alo ni won ri, won ko ri abo e.

Bee la gbo pe awon egbe olokada Acomoran gba egberun meta aabo (3,500) naira lowo won, ti egbe Amoran naa tun gba egberun kan aabo (1,500) naira lowo, tawon ko si ri ipa nkan ti won fowo naa se.

Segun, okan lara awon olokada naa to tun soro so pe ounje tawon ko le je ni awon alaga won n je, nitori gbogbo ere to ye kawon maa mu lo sile fawon ebi won ni won ti gba tan nitori tikeeti.

Lojo Tosde la gbo pe awon olokada naa jade sita lati se iwode ifehonuhan wi pe ki won ba won wo owo naa se, ki won si foju aanu wo awon.

Bo tile je pe ohun ta a gbo tele ni pe alaga naa ti ranse pe awon olopaa SARS lati wa a da iwode naa ru, sugbon ti a pada gbo pe ko si olopaa kan to yoju sibe, ati pe awon agbaagba ilu naa ti be won pe ki won ma se iwode.

Ohun ta a gbo pe o je abajade ipade ti won so pe won se ni pe, won ti pada gbe owo naa kuro ni iye ti won gbe e si, ti won si ti gbe e si eedegberin le laadota (750) naira, bo tile je pe owo naa ko tii te won lorun.

Lati fidi oro naa mule, AWIKONKO gba ofiisi egbe Acomoran lo lati le je ki Ogbeni Basuka ti won fesun kan tan imole si esun ti won fi kan an, sugbon iyalenu lo je fun wa nigba ti Basuka funra e so pe alaga ko si nile.

O so pe ko si nkan toun fe e so le e lori nitori pe ko si oro to jo be e ni Ado-Odo, ati pe ki a lo o so fun eni to ran wa nise pe a ko mo ibi ti a n lo, to si fi ibinu le wa jade.

Leyin e la gbo pe eeyan to lagidi, to si ni igbera ni okunrin naa je, ati pe ko seni to le ba a soro tabi koju e.

Ni bayii, awon olokada naa ti wa rawo ebe sijoba Ibikunle Amosun, alaga egbe Acomoran patapata, Apelogun, awon eleyinju aanu atawon ajafetoo omoniyan wi pe ki won tete gba awon lowo eni to n fi aye ni won lara.

Bakan naa ni won je ko ye wa owo tawon n pa lojumo ko to nkan, owo tikeeti lawon fi n san, tawon si tun fowo tawon ba pa tun okada won se, nitori pe ko si ona to gbadun niluu Atan-Ota.

Ibeere tawon eeyan to gbo soro naa n beere ni pe ki lo fa a ti won ko fi maa ja tikeeti okada naa ninowo tijoba Amosun funra e fowo sii, to si je pe iye owo naa, irinwo (400) naira ni won n ja tikeeti ni Abeokuta to je olu-ilu ipinle Ogun.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI