Ara Temitope to ya were tele ti ya o - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, February 13, 2018

Ara Temitope to ya were tele ti ya o


Nise lenu ya opo awon ara agbegbe oja Ita Ale to wa niluu Oru Ijebu, ipinle Ogun lojo Fraide, ojo kerindinlogbon osu to koja yii nigba ti won ni were olodun pipe kan ti won pe oruko e ni Lateef Temitope Adunni gbadun lasiko tawon akorin ijo Ridiimu ti Baba Adeboye, eka ti won pe ni City of David n se ipalemo orin ti won fee ko lojo Sande to lo lohun.

Iroyin to te AWIKONKO lowo lose to koja yi je ko ye wa pe ni nnkan bi aago mefa irole nisele naa sele, to si ya opo awon araadugbo naa lenu pupo, paapaa awon to gbo sisele kayeefi naa.

A gbo pe adugbo Oke Elesin niluu Ibadan ni Temitope n gbe tele ko too di pe awon aye pa kadara e da, ti won si ya a ni were osan gangan, sugbon ti Olorun tun gba owo awon omo ijo Ridiimu naa woo san.

Emmanuel Ezekiel to fisele naa to wa leti je ko ye wa pe lakoko tawon n se ipade orin (rehearsal) lojo naa ni Temitope n koja lo nihoho, bo se de iwaju soosi lo ba duro, to si bere sii jo si orin tawon n ko.

O ni bo tile je pe olori akorin won ti koko gbo ohun pe kawon gbadura fun obinrin were naa, sugbon to ko eti ikun si ohun naa nitori pe ita soosi naa lo wa, bee lo so pe oju gbogbo awon tawon wa ninu soosi ko kuro lara pelu bo se jo si orin tawon n ko nirole ojo naa.

Odomokunrin Emmanuel naa tun so pe bo se ku die kawon se oore ofe nigba tawon pari ni okan lara omo ijo, ti kii se omo egbe akorin sare wole, to si loo so fun adari egbe akorin pe emi Olorun so foun pe kawon gbadura fun were naa, toun naa si so pe oun ti gbo ohun naa tele, sugbon toun ko eti ikun sii.

O tun je ko ye wa pe lesekese lawon tun bere sii korin tawon si n gbadura pelu itara fun Temitope, toun naa si wo inu soosi wa ba won, to si bere sii se bi won se n se. bee lo tun so pe bi oga akorin se rii lo lo gbe owo lee lori.

AWIKONKO gbo pe bi oga akorin naa se gbe owo le e lori lo ba subu lule, nigba to maa laju ni won rii pe ara e ti ya, to si bere sii beere pe nibo loun wa. Nigba ti won mu bairo ati iwe fun un pe ko ko oruko e, lo ba ko Lateef Temitope Adunni, to si tun je ko ye won pe adugbo Oke Elesin niluu Ibadan loun ti wa.

Lesekese la gbo pe won ti loo fo ori e, ti won si muu lo we, bee la gbo pe won tun se irun min in sii lori, lati le je ko dun un wo loju pada. A tun gbo pe omode ni Temitope, ti ojo ori e ko tii ju odun marundinlogbon lo.

Opo awon to gbo sisele naa ni won n so pe Olorun Baba Adeboye n sise iyanu kaakiri agbaye, lara e ni ti were kan ti won loo gbadun lasiko ipolongo ipago olodoodun ti won maa n se ninu osu kejila odun to koja ni Sango.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI