Eyi L'asiri Iku To Pa Ojogbon Akinwunmi Ishola - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, February 18, 2018

Eyi L'asiri Iku To Pa Ojogbon Akinwunmi Ishola

Titi di bi e ti n ka iroyin yi lopo awon to mo gbajugbaja onkowe nni, Ojogbon Akinwunmi Ishola ni won si n kanminu lori bi baba naa se jade laye l'eni odun mokandinlogorin (79) laaro ojo Abameta Satide to koja yi.

Ojogbon Akinwunmi Ishola to ko awon iwe itan akatunka bii O Le Ku, Efunsetan Aniwura, Madam Tinubu, Olu Omo, Koseegbe, Saworoide, Agogo Eewo ati Campus Queen, eyi ti Kunle Kelani so di sinima agbelewo niroyin fi to wa leti pe ilu Ibadan lo ku si.

AWIKONKO gbo pe o ti le lodun meji ti ilu mooka onkantan naa, eni to satunko iwe itan Ojogbon Wole Soyinka, Ake ko si ede Yoruba naa ti n saisan, tawon ebi si ti n toju e, ko too di pe akuko pada ko leyin omokunrin baba agba naa.

A gbo pe ara Ojogbon Akinwunmi Ishola ti n ya, to si ti gbadun koja siso, sugbon ti oro yi pada laaro Satide naa, to si dagbere faye pelu alaafia.

Lara awon to ba idile Akinwunmi kedun ilu Ojogbon naa ni Aare Muhammadu Buhari, eni to sapejuwe Ishola gege eni to nife igbelaruge asa ati ise, paapaa ede Yoruba, to si muu lokunkundun.

Ninu iwe ibanikedun naa ti Ogbeni Femi Adesina to je alakoso iroyin Buhari ko lo ti so pe gbogbo agbaye lo padanu Ojogbon naa, ti won ko si le gbagbe awon ise to ti se sile ko too jade laye.

Bakan naa ni Gomina Abiola Ajimobi tipinle Oyo so pe kii se molebi baba naa nikan lo padanu e, bi ko se gbogbo omo Yoruba nitori pe okan pataki lara awon to je ki ede Yoruba di gbajumo kaakiri agbaye ni.

Ohun tawon to gbo nipa iku Ojogbon Akinwunmi Ishola n so ni pe olojo lo de ti iku fi muu lo, bi asiko eda ko ba si tii to, ko seni to le pa iru ebi bee.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI