Asiri Iya-Agba So Omo-omo e Mo'le bi Eran Tu l'Abeokuta - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, March 1, 2018

Asiri Iya-Agba So Omo-omo e Mo'le bi Eran Tu l'Abeokuta

Nise lawon ara adugbo Ife-Lagba lagbegbe Obada-Oko niluu Abeokuta la enu won sile lojo Tusde ojo ketalelogun osu kinni odun yi ti won ko si le tete pa a de nigba ti won ri iya arugbo kan, Yemi Kazeem ati omo e, Yomi Kazeez gbimo papo lati so omoomo e, Segun Azeez, omodun mejila mole fun osu meji.

Epe rabande lawon to wa nibi isele naa atawon to gbo nipa e n gbe awon eeyan naa se lori bi won se de omo naa mole, to si je pe oju kan soso lo wa to ti n jeun, nibe naa lo ti n yagbe, to si tun n to sii.

Gege bi a se gbo, won ni aisan kan to fe e jo bii alaganna lo n da omo naa, Segun Azeez laamu, to mu ko maa sa kaakiri igboro Abeokuta, ti won si ni bi won ko ba tete mura si oro e, o see se ko jawo igbo, ki won si ma rii mo.

Iroyin to te AWIKONKO lowo je ko ye wa pe ilu Sagamu ti Segun n gbe lodo awon ebi baba e ni aisan naa ti de si lara, ti a si gbo pe awon ebi baba e kii fun lounje, ti won si tun n fiya je.

Nigba ti wahala naa po ju fun won lo fa a ti won ni iya e, Yomi Kazeem ta a gbo pe odun 2011 loun ati oko e, Wale Azeez ti jo daaru funra won, ti won ko si fera won mo fi loo mu Segun kuro lati toju e nibi toju ti maa to o.

AWIKONKO gbo pe inu osu kokanla odun to koja yi ni Yomi loo mu omo e Segun kuro lodo awon obi to bi baba e, to si muu wa si Obada Oko nibi ti iya e, Yemi n gbe lati toju e.

A gbo pe bi won se mu Segun de lo ti bere iwa e yi, nigba ti wahala naa si poju fun Yomi to je iya-iya e ni won ba pinu lati ra seeni lati de e mole.

Ohun ta a gbo ni pe nigba tasiri maa tu, awon olopaa SARS ni won n sise won koja ladugbo naa, ti won si gburo bi Segun se n pariwo nibi ti won de e mo, ti won si yoju sibe lati mo nkan to n sele.

Lasiko ti won de e mole
Iyalenu lo je fun won nigba ti won ri Segun pelu omije loju, to n bebe wi pe ki won tu oun sile, ati pe iya ti won fi n je oun ti poju.

Awon SARS naa lo ranse pe Komisana olopaa, Ahmed Iliyasu lati wa a foju to isele naa, ti Iliyasu si ranse sawon oniroyin lati wa a wo nkan to n sele.

Nigba to n soro, Yomi to je iya Segun so pe oun ko mo pe bawon se de omo naa mole lodi sofin, ati pe oun gan an loun ronu lati ra seeni tawon fi de e mole nitori pe wahala to n fun iya oun ti poju, ti ko si te oun lorun.

O so pe aimoye igba ni Segun ti ji oun lowo gbe, paapaa to si tun ji foonu oun, tawon ko si le so ibi to fi si titi dasiko yi. Bee lo ni nitori bo se n sa kaakiri lo je kawon de e mole.

Iya agba naa so pe oun sakiyesi wi pe awon aye lo n gbogun ti Segun nitori pe nkan to n se kii soju lasan, o ni agbara oun ko ka Segun lo je koun so fun iya e lati wa bawon se maa so mole.

Omo naa, Segun nigba toun naa n soro so pe ilu Sagamu loun n gbe lodo awon obi to bi baba oun tele ko too di pe iya oun wa a mu oun kuro nibe nitori iwa ti won loun n hu.

O so pe oun sakiyesi wi pe enikan lo fi oogun na oun nigba toun wa ni Sagamu, latigba naa loun ti bere sii sa kaakiri, toun si tun ma a n jale, eyi to fa a ti won ko fi ran oun lo sile iwe mo.

Nigba toun naa n soro, Iliyasu so pe odaju abiyamo ni Yomi ati iya e, Yemi nitori pe ko si abiyamo gidi to le ronu lati so omo won mole bi eran agboole ti won fe e pa je, di po ki won wa ona abayo si aisan to n yo o lenu.

O ni edun okan lo je foun pelu ipo tawon ba omo naa, to je pe oju kan soso ti won de e mo lo yagbe sii, to si ti to sii, ti won ko fun un lounje daadaa.

O wa seleri wi pe awon ko ni foju aanu wo Yomi ati Yemi fun iwa ti won hu naa, nitori pe se lawon yoo fiya je won labe ofin.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI