Owo Te Alaaji Godonu, Ogbologbo Omo Egbe Okunkun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, March 1, 2018

Owo Te Alaaji Godonu, Ogbologbo Omo Egbe Okunkun

Beeyan ba de ilu kan ti won pe ni Owode-Egbado nipinle Ogun lojokokanlelogun osu kinni, to ri bawon ara ilu naa se n jo, ti won n yo nigba towo olopaa te ogbologbo omo egbe okunkun, Michael Agbeyangi tawon olopaa ti n wa lati nkan bii odun meta seyin yoo mo pe ko si nkan meji ti won n dunnu le lori bi ko se alaafia to tun pada wonu ilu naa wa ba won losan gangan.

Ohun ta a gbo ni pe latigba ti Michael tawon eeyan mo si Alaaji Godonu wonu ilu Owode-Egbado ni alaafia ti salo latari bawon omo egbe okunkun se n fojoojumo pa ara won, ti won tun n kawon araalu to je alaise.

Awon araalu naa la gbo pe won ko le sun oorun asundokan nitori pe tosan toru ni Alaaji Godonu atawon emewa e fi n sise buruku won, ti won ko si fokan awon araalu naa bale.

Odun 2015 la gbo pe Alaaji Godonu pelu awon omo egbe okunkun e da wahala nla kan sile, nibi ti won ti f'emi opo awon eeyan sofo, bo tile je pe owo te ninu won, sugbon toun na papa bora, to si je pe latigba naa lawon olopaa ti n wa.

Nigba tasiri e maa tu, nise lo tun wonu ilu naa wa nirole ojo naa, lero wi pe won yoo ti gbagbe isele naa, ti won ko si bii ri toun ro, lai mo pe iyan ogun odun e si n gbona felifeli lodo awon olopaa.

Lara awon ti won farapa nibi isele naa ti won rii lopopona Ado-Odo la gbo pe won tawon olopaa lolobo, ti won si gbera lati loo tete mu bale ko to di pe o tun fese fe e.

Okan lara awon to fidi isele naa mule fun wa je ko di mi mo pe nigba towo palaba e segi, nise lo kawo lori, to si so pe "o pari".

Agbenuso olopaa, Abimbola Oyeyemi nigba toun naa n fidi isele naa mule so pe DPO agbegbe naa, Ogbeni Muritala Agboola lo sare lo sibi ti won ti ri ogbologbo omo egbe okunkun naa mu nibi to sapamo si.

O ni iyalenu lo je pe nigba tawon maa muu, awon eroja oloro bii aake, ida oloju meji atawon oogun abenu gongo ni won ba lowo e, ti won si gba a.

Abimbola wa a je ko ye wa pe Komisana won, Ahmed Iliyasu ti pase pe ki eka ileese won to n ri soro ajinigbe ati egbe okunkun bere ise iwadii siwaju sii lori e, lati le jewo awon to tun ku e.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI