Asiri Omoniyi, ayederu agbejoro tu l'Abeokuta - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, March 1, 2018

Asiri Omoniyi, ayederu agbejoro tu l'Abeokuta

Bi kii ba a se ifura tawon osise kootu Isabo niluu Abeokuta ni si okunrin kan ti won pe oruko e ni Omoniyi Vacoster, eni ti won lo n fise ati aso agbejoro lu awon eeyan ni jibiti owo, bo ya ki ba mai ti ronupiwada dasiko yii.

Ojo Aiku Sande ojo kerin osu to koja yi ni agbenuso fawon olopaa ipinle Ogun, Ogbeni Abimbola Oyeyemi firoyin Omoniyi to AWIKONKO leti, nibi to ti so pe okunrin naa ti n ka boroboro pe ki won se oun jeje, atije lo sun oun de be.

AWIKONKO gbo pe ojo ti pe ti Omoniyi ti maa n gba ise lowo awon eeyan, to si maa lo si kootu lati jeri gbe won, lai mo pe ko tii kun oju osuwon lati di eni ti won le maa pe ni agbejoro, depodepo pe yoo gba ise.

Okan lara awon omo egbe agbejoro nipinle Ogun, Arabinrin Omomehin Oluwatoyin la gbo pe o fura si Omoniyi wi pe kii se ara won, ti won ko si tii fun niwe eri gege bi agbejoro, ko to o di pe o loo fejo e sun DPO olopaa to wa ni Ibara, Abeokuta tawon yen si bere igbese lati sewadi e.

Omomehin tun so fawon olopaa pe aimoye igba lawon ti ri Omoniyi kaakiri inu kootu, nibi to ti n gbejoro fawon eeyan, eyi to mu kawon bere iwadii lori e, tawon si rii pe won ko tii pe segbe awon agbejoro.

Lesekese ti DPO naa ti gbo lo ti ran Ogbeni Dada Olusegun to je igbakeji e lati lewaju awon olopaa ti yoo lo mu okunrin naa, ki won si sewadi e, towo si te e lojo Tosde to koja yii.

Nigba to n soro, Omoniyi so pe looto loun ko tii di agbejoro, bo tile je pe oun ko eko nipa ise agbejoro nile iwe giga Yunifasiti, sugbon toun ko tesiwaju lati lo sileewe ti won yoo ti so oun di ojulowo agbejoro.

O tesiwaju pe ki won foriji oun nitori airikansekan lo je koun gbegba agbejoro lati ma se gbagbe awon eko toun ko nileewe, bo tile je pe o si ni lokan lati kawe sii, koun si gba iwe eri nidi ise naa.

Ahmed Iliyasu to je Komisana olopaa ti wa a pase pe ki eka ileese won to n ri si iwa odaran, iyen State Criminal Investigation and Intelligence Department, SCIID tesiwaju lori lori ejo naa, ki won si rii pe won foro wa a lenu wo daadaa lati tun mo iru eeyan to je lawujo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI