Egbe Osere Tampan Da Egbe Osere Apapo Ipinle Ogun Ru - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, March 1, 2018

Egbe Osere Tampan Da Egbe Osere Apapo Ipinle Ogun Ru

Titi di asiko ti a n ko iroyin yi ni nkan ko fi be e rogbo laarin egbe osere omo bibi ipinle Ogun ti a mo si Ogun Indigenes Entertainment Professional Forum ati egbe osere TAMPAN nitori bi won se ni lara awon omo egbe osere TAMPAN se fe e fo egbe naa si wewe.

Yemi Adegunju
Idi abajo ni ti leta ti won lawon oloye egbe osere TAMPAN lapapo te sinu ateranse awon omo egbe won ni kookan pe ki won ma se kopa ninu eto ti egbe osere omo bibi ipinle Ogun ba n se mo.

Iyen nikan ko, se ni won ko lati kopa ninu ere ori itage ti won se fun gomina Ibikunle Amosun lakoko to n sayeye ojo ibi ogota odun (60).

Iwadii AWIKONKO fi ye wa pe Yemi Adegunju to je okan lara agba osere TAMPAN, sugbon ti kii se omo egbe osere omo bibi ipinle Ogun ni won lo fi leta naa ranse si awon omo egbe e nipinle Ogun.

Bo tile je pe oro naa ko je kayeefi fun awon osere to gbo, nitori bi won ni won se fi ote sa kuro ninu egbe osere ANTP ni yen.

A tun gbo pe se lawon omo egbe osere TAMPAN n so ara won lowo ati lese lati rii pe omo egbe won kankan ko ba egbe osere omo bibi ipinle Ogun, Ogun Indigenes se po mo.

Awon osere to ba wa soro so pe ko ye ko je pe enu Yemi Adegunju lo ye kiri leta bee ti jade, nitori pe omo Ibadan ni, idi ni yii tawon kan fi so pe atoko wa ba ile je ni.

Bakan naa la tun gbo pe egbe osere TAMPAN yi tun ti n gbiyanju lati da egbe osere miran sile, eyi ti won pe ni Ogun Citizens, tawon kan so pe Olaiya Igwe lo n sakoso e labele.

Kehinde Soaga
Won ni nitori pe Kehinde Soaga to je alakoso ati eni to da egbe apapo osere omo bibi ipinle Ogun sile ti loo gba ise lodo ijoba apapo lai pe yii lo tun je ki inu bi opo won, ti won fi lawon ko ba won sise papo mo.

Ninu oro Yemi Adegunju to ba oniroyin wa so lori foonu, o so pe looto loun fi leta ranse sawon omo egbe pe ki won ma ba egbe osere omo bibi ipinle Ogun se papo mo, ati pe lodo awon Oloye egbe lapapo ti won je oga won ni ase naa ti wa.

O salaye pe funra akowe ijoba ipinle Ogun, Amofin Taiwo Adeoluwa lo pase pe kawon ma ba enikeni se papo mo nibi ti eleyameya ba ti wa, idi ni yii tawon fi yera.

Bakan naa lo so pe eleyameya wa ninu egbe apapo osere omo bibi ipinle Ogun, nitori boun se wa yi, ati Mista Latin pelu Odunlade Adekola, awon ti pe nipinle Ogun daadaa, awon si ti di omo bibi ipinle Ogun nipa ofin ile wa, sugbon ti won ko gba won si egbe apapo osere omo bibi ipinle Ogun.

Bee lo tun fi esun kan Kehinde Soaga to je olori egbe naa pe oun gan an lo n da egbe naa ru, nitori gbogbo eto to ye ko kan omo egbe lo n da sapo ara e.

Sugbon Kehinde Soaga so pe, ko seni ti ko mo Yemi Adegunju gege bi oniro laarin awon osere. O ni atoko wa ba ile je ni, nitori kii se omo ipinle Ogun rara, omo ipinle Oyo ni.

O tun salaye pe ko sigba kan ti Taiwo Adeoluwa to je akowe ijoba ipinle Ogun so pe ki egbe osere kankan ma ba egbe apapo osere omo bibi ipinle Ogun se papo, nitori egbe to sunmo ijoba ni, topo awon osere si ti je anfaani pupo labe won.

O ni ki Yemi Adegunju bo sita, ko wa so gbogbo awon eto toun ko sapo, tabi toun da sapo ara oun.

Kehinde Soaga tun so pe nkan to n fa re e ti awon omo egbe osere bi awon olorin se n sa fun egbe osere TAMPAN lati ba won se papo, nitori pe iwa ti won hu, ti won fi fi ote tu egbe ANTP ka ni won tun fe e gbe wo egbe apapo osere omo bibi ipinle Ogun, sugbon ti Olorun ko ni gba fun won.

O ni won ko mo ju ki won fi owo se apapin lai ni ajeseku, idi ni yii ti opo won fi n wa ona lati da egbe ru.

Sugbon ni bayii, egbe osere TAMPAN ti yari pe ki ijoba maa ba won dowopo taara lai si labe egbe apapo osere omo bibi ipinle Ogun, Ogun Indigenes, sugbon tawon osere yooku so pe yoo soro lati se, nitori igberaga lo n da won laamu.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI