Awon Fulani sa Owolabi aburo Oba Afon pa sinu oko e - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, March 1, 2018

Awon Fulani sa Owolabi aburo Oba Afon pa sinu oko e

Ko seni to gbo soro awon Fulani darandaran ti won tun seku pa baba agbalagba agbe kan ti won poruko e ni Owolabi Adetona sinu oko e niluu Afon nijoba ibile Imeko-Afon, ipinle Ogun lojo Tosde ojo kejidinlogun, osu kinni odun yi ti ko maa gbe awon odaran naa sepe pelu awon iwa buruku ti won n hi kaakiri orileede Naijiria.

Gege bi iroyin to te AWIKONKO lowo se so, won ni kii se Owolabi ti won ni aburo Oba Afon ni nikan ni won seku pa lojo Tosde naa, won ti koko pa agbe min in, Ige Ogun sinu oko e ni labule Asa laaro ojo naa.

Ohun ta a gbo ni pe ko tii ju wakati merin tijoba ipinle Ogun labe Gomina Ibikunle Amosun gbe ipinu kan dide lati dena wahala laarin awon Fulani atawon agbe nipinle naa ni won huwa buruku yi.

AWIKONKO gbo pe awon Fulani yi lo da maalu won wo inu oko Owolabi yiti won lojo ori e ti le ni ogota odun to gbin efo, paki ati isu si lati jeun, ti won si ti fe e je gbogbo oko naa tan.

Asiko yi la gbo pe Owolabi rin sasiko to si sare loo ba won lati beere idi ti won fi n je kawon maalu won maa je oko toun da, ti won si fe e da oun ni gbese.

Lara awon to fisele naa to akoroyin wa leti je ko di mi mo pe awon Fulani naa ko da Owolabi lohun, kaka ki won da a lohun, ni se ni won diro mon on, ti won si bere sii fi ada owo won sa a.

Won ni nigba ti won rii pe emi ti fe e jabo lara ni won sare dari awon maalu won kuro nibe, ti won si salo ki asiri won ma ba a tu sita, bo tile je pe a gbo pe owo ti te okan lara won.

Igbe Owolabi la gbo pe o je kawon to n koja lo tete mo pe nkan sele ti won si sare de be lati mo nkan to sele, iyalenu ni won lo je nigba ti won ba a ninu agbara eje, ti won ri apa ada lara e lorisirisi.

Oku Owolabi
Awon to fisele naa to wa leti tun je ko ye wa pe asiko ti won fe e gbe Owolabi lo si osibitu to wa nitosi lo dagbere faye, bee la gbo pe irole ojo naa ni won pada sin in nilana Musulumi.

Okunrin kan to ni ka foruko boun lasiri lo je ko ye wa pe okan lara awon aburo Oba ilu Afon ni Owolabi je, ati pe awon ebi ti so pe afi kawon olopaa tete bere igbese lati ri won mu.

Bi tile je pe alukoro fawon olopaa ipinle Ogun, Ogbeni Abimbola Oyeyemi ti koko so pe awon ko tii gbo sisele naa, sugbon to pada so fun wa pe owo ti te okan lara awon Fulani naa, ti iwadii si n lo lowo.

O so pe oun yoo je ka mo ibi tawon ba oro naa de lai pe, sugbon ti a ko tii gbo nkankan titi dasiko ta a sakojopo iroyin yi tan.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI