Die Lo Ku Ki Kolade Onanuga Padanu Emi E - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, February 19, 2018

Die Lo Ku Ki Kolade Onanuga Padanu Emi E

Titi di bi e ti n ka iroyin yi lowo ni gbogbo ebi atawon ololufe ilu mooka olorin Fuji nni, Kolade Onanuga, eni to tun n korin bii Wasiu Ayinde si n ba a dupe lori bi Olorun se doola emi e nibi ijamba ina kan to sun moto e, SUV.

Gege bi iroyin to te AWIKONKO lowo lai pe yi se so, won je ko ye wa pe agbegbe Erunwo nitosi Ijebu Ode, ipinle nisele aburu naa ti waye, ti moto e si jona di eeru.

A gbo pe Kolade Onanuga ati alabasisepo (personal assistant) e la gbo pe won wa ninu moto lakoko naa nigba to kofiri wi pe moto e n yo eefin jade latinu enjiini (engine).

Lesekese la gbo pe Kolade ti ati amugbalegbe e ti sare bo sile lati loo wo nkan to n sele, to si je pe gbara ti won bo sile ninu moto naa ni ina nla la jade, to si mu ki won sa bo sile.

Bo tile je pe a ko tii gbo oro lati enu okunrin olorin taye n gba ti e lasiko yi, ti a si n mu da a yin loju pe a maa mu ekunrere iroyin naa wa fun un yin lai pe. E ku oju lona.No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI