Titi
di bi e ti n ka iroyin yi lowo lawon olopaa si n wa odomokunrin eni odun
mokanlelogun (21) kan, Mayowa ti won nise birikila lo n se, eni ti won fesun
kan wi pe o fipa bomodun mokanla sun.
Ni
nkan bi aago mejo kuseju meedogun ale ojo Sande ose to koja la gbo pe Mayowa
fipa wo omo naa lo sile akoku kan to wa legbe soosi kan ta a foruko bo lasiri,
iyen leyin banki Zenith to wa ni Isale Igbeyin, Abeokuta.
Gege
bi won se fi iroyin naa to AWIKONKO leti, a gbo pe omodebinrin naa ta a foruko
bo lasiri sese pon omi ti won fe e lo nile tan ni, sugbon to ti bo bata e sidi
konga to ti loo pon omi.
Bata
yi la gbo pe omodebinrin naa fe e lo o ko, ko too di pe o pade Mayowa, to si
fogbon tele e wi pe oun fe e mu debe lai mo pe ise buruku to fe e se ti wa ninu
e, ati pe won ni Mayowa sunmo ebi omodebinrin yi, tiyen ko si lero wi pe o le
se buruku soun.
Bi won
se de ile akoku kan to wa legbe soosi nitosi ibi tomo naa ti loo ponmi ni
Mayowa fogbon tan an wobe, to si sare bo pata omo yi, to tun fowo sii lenu lati
ma pariwo kawon eeyan to wa nitosi le mo nkan to n lo.
Loun
naa ba tun sare bo sokoto e, to si gbe kinni abe e somo naa nidii, to fipa ja
ibale e. Omo naa la gbo pe o sunkun lo sodo awon obi e lati loo fejo sun, tawon
yen si faraya lati loo gbe ija lu Mayowa, sugbon ti Mayowa funra e ti na papa
bora ki won to o de.
Afemojumo
ojo Monde to koja ni won tun un lo ji ka Mayowa nile, ti won ko si ba a, sugbon
tawon obi Mayowa n ba omo won bebe wi pe ki won maa loo fi olopaa muu, sugbon
tawon yen ti gba tesan lo lati loo fi to won leti.
Awon
olopaa naa ti wa seleri wi pe bi Mayowa ko ba a yoju si won lati gbo tenu e,
towo awon ba te e, esun tawon yoo fi kan niwaju adajo ko nii te e lorun, sugbon
ta a gbo pe omokunrin naa ko tii yoju titi ta a fo sakojopo iroyin yi tan.
No comments:
Post a Comment