Oogun Owo Ni Mo Fee Fi Ori Oku Se - Alex - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, March 1, 2018

Oogun Owo Ni Mo Fee Fi Ori Oku Se - Alex

Kani odomokunrin eni odun marundinlogbon (25),  Babalola Alex ati ore e ti won n pe ni Ijebu toun tin a papa bora mo pe omi yoo pada wogbin won lenu latari oogun owo ti won fe e se ni, boy a won ki ba ti duro de asiko Olorun fun ayanmo won.

Ni nkan bi aago mejila osan ojo Tosde ose to koja la gbo pe asiri Alex ati ore e tu sita lagbegbe Asese nipinle Ogun lasiko ti won loo hu ori oku ti won ti sin tipe nite oku kan lagbegbe naa.

Okan lara awon to n gbe lagbegbe naa la gbo pe o ta awon olopaa SARS lolobo lasiko tawon yen n sise koja. Okunrin naa la gbo pe o so fawon SARS naa wi pe asiko toun loo yagbe ninu igbon loun ri awon ore meji naa ti won n ki nkan to jo ori oku bo inu baagi ti won gbe dani.

Lesekese tawon olopaa naa ti gbo ni won ti sare lo sibe lati look o won, sugbon nigba ti won maa de be, Alex nikan ni won ri pelu baagi owo to gbe dani.

Bo tile je pe se ni Alex koko paro fawon olopaa naa nigba ti won n beere lowo e pe ki lo wa ninu baagi to gbe dani pe aso toun fe e lo fo lo wa ninu e, sugbon nigba ti won maa tuu, iyalenu lo je pe ori oku lo wa ninu e.

Basiri e se tu sita lo ti bere sii bebe wi pe ki won se oun jeje, ati pea won meji ni, tenikan to ku ti salo nigba to kefiri pea won SARS ti n bo. Alex so pe odo babalawo toun ati ore oun to n je Ijebu lo lati lo dogbon soro ara won, nipa si se oogun owo lo ni kawon loo wa ori oku wa, idi ni yii tawon fi loo hu ori oku naa.

Awon SARS naa la gbo pe won tun ko won lo sodo Baale Asese, Oloye Kasumu Sonola to bu enu ate lu iwa tawon eeyan naa hu, bee lo rawo ebe sawon olopaa na wi pe ki won tubo bawon sise lati ri awon odaran naa mu.

Bi iroyin naa ti kan Komisana olopaa, Ahmed Iliyasu leti lo ti pase pe kawon SARS tesiwaju ninu ise iwadii won, ki won si tubo foro wa Alex lenu wo lati ri Ijebu to salo mu, kawon le tete bere igbese lati foju won bale ejo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI