Emi Kii Se Oloselu Afenuje – Onarebu Gbeleyi - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, March 30, 2018

Emi Kii Se Oloselu Afenuje – Onarebu Gbeleyi

Oludamoran fun ijoba ipinle ogun lori oro ina monamona, Rt. Onarebu Olusegun Bola Gbeleyi ti so pe oun kii se oloselu alafenuje ti ko mo nkan to n se, bi ko se oloselu to dangajia lati di eyikeyi ipo oselu mu lorileede Naijiria.

Onarebu Gbeleyi
Onarebu Gbeleyi to tun figba kan je igbakeji olori ile igbimo asofin agba nipinle Ogun nigba isejoba Oloye Olusegun Osoba gege bi gomina soro naa niluu Abeokuta lojo Wesde to koja yi lakoko to n farahan awon agbaagba ile Yewa lapapo (Ogun West Council of Elders) lori ipinu e lati dupo Seneto fun ekun Ado-Odo/Igbesa ninu idibo odun 2019 to m bo lona.

Nibi ifarahan naa ti Ogbeni Taiwo Akinsanya Fagbemi to je oludamoran pataki ati olori eka eto ina monamona nipinle Ogun ti lewaju awon iko to tele Onarebu Gbeleyi to tun je Otunba niluu Igbesa lo ti so pe inu oun yoo dun bawon agbaagba ile Yewa ba le yan oun gege bi eni ti yoo soju ekun naa nile igbimo asofin agba l’Abuja lodun 2019.

Otunba Gbeleyi so pe bo tile je pe oun kii se omo kekere nidi oselu, paapaa toun mo awon ojuse oun nipa ipo toun n lo fun naa, nitori awon iriri toun ti ni nigba toun fi wa gege bi igbakeji olori ile igbimo asofin lodun 1993 sodun 2003.

O ni bii igba toun tun fe e lo fi eran je eko ni ipo toun n lo fun naa, ti inu oun yoo si tun dun lati soju awon eeyan oun ni Yewa paapaa, nijoba ibile oun, Ado-Odo/Ota.

Gbeleyi to ti lewaju awon abadofin, to si ti sagbateru awon aba to ti dofin lorisirisi lakoko to fi wa nile igbimo asofin tun so pe nigba toun ba de ipo naa pelu ogo Olorun, oun ko nii gbagbe awon agbaagba naa pelu awon toun loo soju, nitori pe idagbasoke ati ilosiwaju agbegbe oun lo je oun logun.

Nigba to n gba enu awon igbimo agbaagba Yewa naa soro, Oloye Kola Bajomo to jokoo gege bi alaga igbimo agbaagba Yewa lojo naa dupe gidigidi lowo Onarebu Gbeleyi pelu awon ipa to ti ko nigba isejoba Oloye Olusegun Osoba, ti ko si seni ti ko le fowo e soya pe looto lo kaju osuwon.

O nib o tile je pe awon ko le so pe awon ko mo Otunba Gbeleyi ri, tawon si mo ise takuntakun to se, ti ko si pa enikeni ti nigba ti agbara wa lowo, o ni inu oun yoo dun bawon eeyan ba tun le dide lati dibo yan an lodun to m bo.

Bee lo so pe bo tile je pe awon ko le fokan e bale pea won ti setan lati sagbateru, tabi kawon pinu lati fa a kale, nitori pe oun nikan ko ni yoo je eni akoko ti yoo wa fara han won lati dupo naa, tawon kan ti wa a ba won lori ipo kan soso, si be awon gbodo gba a lamoran pe ko dide lati loo sawon ibi to ba ye ko lo lati tun loo farahan won, ko si so ipinu e fun.

Lara awon agbaagba ile Yewa to wa nibi ipade naa ti won se ninu ile Oloye (Diakoni) Poju Adeyemi to wa ni Ibara ni Seneto Kola Bajomo; Oloye E. A. Edun; Oloye B. A. Ajibabi; Oloye Adeboye Fabuyi; Oloye Onarebu Kunle Elegbede; Oloye T. K.  Aina; Onarebu S. O. Dada; Alaaji Soji Olusesi; Ogbeni Akeem Fagbemi atawon min in.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI