Ipinle Ogun Gbalejo AareAare Teleri Lorileede Mexico - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, March 20, 2018

Ipinle Ogun Gbalejo AareAare Teleri Lorileede Mexico

Ese ko gbero ninu gbongan ayeye asa, iyen June 12 Cultural Centre to wa ni Kuto niluu Abeokuta nibi ti ijoba ipinle Ogun labe Gomina Ibikunle Amosun ti gbalejo awon eeyan jankanjankan kaakiri agbaye bii Aare teleri lorileede Mexico, Ogbeni Felipe Calderon nibi eto olojo meji fawon olokoowo kaakiri agbaye, iyen Ogun State Investors’ Forum.
 
Lara awon to tun wa nibi eto naa to bere lonii ojo Isegun Tusde ni Ogbeni Mo Gawdat Salam to je Olori egbe awon osise fun ileese Google X; Arabinrin Delphine Sangodeyi; Dokita Norbert Volker; Igbakeji Aare orileede yi, Ojogbon Yemi Osinbajo; Minisita feto isuna, Arabinrin Kemi Adeosun; Minisita feto Ogbin, Ogbeni Audu Ogbeh atawon min in.
Nibe ni Igbakeji Aare, Ojo Yemi Osinbajo ti gba ijoba ipinle Ogun ati ijoba ipinle Eko lamoran wi pe ki won fowosowopo nipa eto oro aje, ki ile Yoruba le tubo dagba soke sii laarin awon ipinle to ku lorileede yi.

Osinbajo so pe lai pe yi nijoba ipinle Eko labe Gomina Ambode sepade ajosepo leka eto oro aje pelu ijoba ipinle Kano, ti won si jo dunadura lori bi ipinle mejeeji se le ni ajosepo to dan monran nipa eto oro aje.

Igbakeji Aare so pe bi ijoba ipinle Eko ba le se iru nkan bayii, ko si nkan to di ipinle Ogun lowo lati ni iru ajosepo bee pelu ipinle Eko paapaa bi won tun se jo fegbekegbe, dandan ni ki ajosepo to dan monran wa laarin awon ipinle mejeeji.

Bakan naa lo so pe ko si ani-ani wi pe ipinle Ogun ti di orisun fawon ise fawon ipinle to ku lorileede yi, ti won si ti n wo awokose Gomina Amosun.

Ninu oro ti e, Aare teleri lorileede Mexico, Ogbeni Felipe Calderon gba ijoba ipinle Ogun lamoran wi pe ki won tun wa awon ona ti yoo mu idagbasoke ba ipinle naa nipa ironu to ye kooro.

O so pe lara awon nkan to n fa orileede seyin nipa idagbasoke ati ilosiwaju leka eto oro aje ni iwa ajebanu, ati iwa imotara-eni-nikan, nitori kijoba gbiyanju lati wa iyanju si eyi.

Nigba toun naa n soro, Gomina Amosun dupe lowo awon alejo to fiwe pe sibi eto naa, to si so pe nigba tawon maa bere eto yi lodun 2012, opo awon eeyan ni won n kan sara, ati pe ni bayii, ipinle Ogun ti gberegejige.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI