FUNMILAYO OLOYE SAYEYE OJO IBI AIRO-TELE FUN OKO E, FILEFUN ONI TIATA L’ABEOKUTA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, March 4, 2018

FUNMILAYO OLOYE SAYEYE OJO IBI AIRO-TELE FUN OKO E, FILEFUN ONI TIATA L’ABEOKUTA

Titi di bi e ti n ka iroyin yi ni ayeye ojo ibi odun marundinlaadota (45) airo-tele ti Arabinrin Oluwafunmilayo Oloye se fun okan lara awon gbajumo osere tiata to filuu Abeokuta sebugbe, Ogbeni Oluwadamilare Agbejo tawon eeyan mo si filefun si n je fun okunrin naa funra e, nitori nkan ti ko ri tii tele ni, ati pe Funmilayo to sayeye ojo ibi naa ko si lorileede Naijiria, to fi gbe eto naa kale.
Ni nnkan bi aago mefa aaro ana, ojo abameta Satide to je ojo ayajo ti won bi Oluwadamilare to tun je oludari fiimu la gbo pe Funmilayo pe Filefun ti won jo n fe ara won lori aago lati kii ku ayeye ojo ibi, to si so pe ko loo paaro aso e, nitori toun fe e wo aso to fe e wo.
A gbo pe se ni Filefun so pe ko tii ya nitori pe ile ko tii mo dada, sugbon ta a gbo pe Funmilayo so pe oun sa a fe e ko dide lori beedi lati loo sengi aso e, lai mo pe nkan to fe e se wa lokan e.
AWIKONKO gbo pe Funmilayo ti foro naa to die lara awon osere tiata to sunmo Filefun, iyen awon bii Kayode Akindina tawon eeyan mo si Mista Paragon leti wi pe oun fe e sayeye ojo ibi airo-tele fun oko oun, toun ko si fe e ko mo, nitori naa, ki won lo ba oun ji ka a mo ile, pelu orin “Api baide tuu yuu.”
Nigba to maa di aago meje koja iseju marundinlogbon (7:25am) la gbo pe Mista Paragon, Abiola atawon bii meloo kan de sile Filefun to wa ladugbo Oke-Aregba niluu Abeokuta peluu keeki atawon oti elerindodo lorisirisi, lakoko ti omo olojo ibi funra e si wa lori beedi.
 Iyalenu lo je fawon ti won jo n gbe ile, paapaa onile (landlord) Filefun nigba to ri bi moto se tele ara wonu ogba ile e, paapaa bi eni tun se je ojo ti won sayeye odun Lisabi, tijoba si ti pase koni-o-gbele fawon araalu.
Yiyoju ti Oluwadamilare maa yoju sawon eeyan naa lati inu yara e, oti ni won da lee lori, ti won si korin “Api baide tuu yu” fun un, debi pe omi fe e le maa bo loju e.
Nigba to n soro, Oluwadamilare so pe oun ko nii lero wi pe oun yoo jade lo sibi Kankan, depodepo wi pe oun yoo sayeye ojo ibi oun. O ni nkan to wa lokan oun ni pe leyin toun ba gbadura tan, koun tun loo sun pada, koun si maa wo telefisan ninu yara oun tile maa fi suu.
O ni o kan ya oun lenu nigba tiyawo oun so pe koun dide lati lo paaro aso oun, nitori toun fe e mo iru aso toun fe e wo. O loun so pe ko tii ya nitori pe ko tii to asiko toun fe e jade, ati pe oun ko nii lero lati lo sibikibi.
Filefun so pe iyalenu lo je foun pe won sayeye iyanilenu foun, ti ko si seni to je koun gbo ninu awon to sagbekale eto naa foun.
Emir Kayode Akindina nigba toun naa n soro so pe, okan Pataki lara awon omo toun feran nidi ise tiata ni Oluwadamilare Agbejo, toun ko si le foro e sere nitori pe eni to se e fokan tan ni. O wa gba a lamoran wi pe ko ronu lati fi awon iwa to ku die kaato to n hu sile, nitori pe odun marundinlaadota kii se omode.
Ogbeni Nasirudeen Ogunbiyi to je onile Filefun, eni to so pe ko tii ju odun meji to ti n gbe ile oun nigba to n sapejuwe e gege bi eni teeyan ko gbodo fi sere ni Filefun, ati pe oun ko muu gege bii pe oun loun gbe ile fun, o loun mu gege bi ore. Bee lo gba a lamoran pe ko tubo tesiwaju ninu ise rere to n se.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI