Nitori Obasanjo; GNI ati Paseda di Ore Ojiji - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, March 1, 2018

Nitori Obasanjo; GNI ati Paseda di Ore Ojiji

Peluu bi nnkan se n loo bayii, afaimo ko ma je pe gbogbo ona ni Omooba Gboyega Nasiru Isiaka (GNI) to je oludije gomina labe egbe oselu PDP ninu ibo to waye lodun 2015 n wa lati rii pe ko tun ba ijakule pade ninu ibo to n bo lodun 2019 nitori bi won se  lo n wa ojurere Otunba Rotimi Paseda toun naa je oludije gomina labe egbe oselu UPN.

Opo awon to gbo pe awon mejeeji pade nibi eto ti ti GNI se niluu Sagamu nibi ti Paseda naa ti wa nibe loro naa n se ni kayefi, ohun to tun wa jo awon eeyan loju ni oro tawon mejeeji tun so lojo naa nibi ti won ti fi igbekele won han si egbe tuntun ti Oloye Olusegun Obasanjo sese da sile, eyi ti won pe ni CMN.

Bo tile je pe latigba ti won ti da egbe naa sile lawon oselu kan ti n bu enu ate luu sugbon kaka kawon mejeeji naa se bee, se lawon fi igbekele won han pe egbe naa lo le mu isoro to n dojuko orile ede yii.

Ohun tawon eeyan ko mo ni pe nnkan tawon oloselu mejeeji naa ti won tun je oludije n se ye won, idi ni pe titi di akoko yii, ko ti si egbe oselu to se fokan tan ninu won egbe oselu meji tokiki won po iyen APC ati PDP, kaka ko san lara iya aje won se lo n fojoojumo bi obinrin bee ni wahala egbe oselu mejeeji.

Ati pe lojumo to mo loni in eni ti yoo ba se gomina ipinle Ogun, o gbodo lowo ebora Owu iyen Oloye Olusegun Obasanjo ninu, nitori e lo se je pe GNI atawon oludije min in ko se foro e sere laarin iseju kan, o le da gbogbo nnkan ti won ti n ba bo tipe ru.

Idi niyii ti GNI ati Paseda se mo nnkan ti won so, e e ma se je ko ya yin lenu pe o le di ola kawon mejeeji so pe inu egbe CMN lawon yoo ti jade, nitori pe GNI ko ti mo egbe oselu ti yoo ba jade bee naa lo si je pe egbe UPN ti Paseda wa, ko rinle to, o si tun le mu ijakule wa.

Ninu oro ti GNI so lojo naa lo ti so pe “A nilo lati je ki oju awon eeyan wa la daadaa, ti won si gbodo kopa ninu oselu, a sit un nilo lati sagbateru ijoba to ba dara. Nigba ta a wo awon idi ati Pataki idasile egbe yii, fun apeere NIM ati CMN, a nilo lati tele so po mo liana ti won fi da won sile.”

O loju awon ti la si asise tawon ti se seyin, tawon araalu naa si ti mo awon asise tawon naa ti se, eyi lo fa a tawon fi gbodo gba egbe yii tokantokan. bee lo so pe apeere rere lo je pe Otunba Paseda wa nibi ipade naa, nitori iru tawon eeyan tawon n fe niyen.

Bakan naa ni Paseda ni ti e so pe nigba ti GNI pe oun, to si so Pataki ipade naa foun, toun si ri ipa ti yoo ko, lo je koun yoju, nitori pe awon eeyan tyo ba ni afojusun gidi lo ye kawon jo maa se po.

Ninu oro e lo tun so pe “Opo nkan la ti se ti ko si ayipada rere. Nigba ti egbe kan ba dide, egbe min in yoo dide tele. Awon eeyan ti ni suuru to fun egbe oselu APC ati PDP, ni bayii, nnkan to yato ni won n fe e. Mi o nii so pe ayipada (Chage), sugbon maa so pe nkan to yato.”

Siwaju sii lo so pe oselu ni nnkan se pelu kawon agbajowo, nitori pe lai si agbajowo, ko le si isokan ati ife, tawon si gbodo duna dura. O wa fi kun un oro e pea won niloo awon eeyan tuntun nijoba lodun 2019.

Awon oloselu kan ti won mo bo se n loo nipinle Ogun so pe gbogbo nnkan to n sele ko seyi to sokunkun si Amosun nibe, nitori ibi ti Obasanjo ba n loo fun ti ipo gomina 2019 ni Gomina naa n loo sugbon won ko ti fee ko dariwo bayii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI