Wahala De Sinu Egbe PMAN Nipinle Ogun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, March 1, 2018

Wahala De Sinu Egbe PMAN Nipinle Ogun

Bi iroyin to n lo kaakiri igboro nipa egbe apapo olorin nipinle Ogun, iyen egbe Performing Musicians Association of Nigeria (PMAN) ba fi le je otito oro, a je pe a fi kawon omo egbe naa tete fimo sokan lati gba alaafia ati isokan laaye ninu egbe lati dekun wahala ojo iwaju.

SAMMY B
Gege bi iroyin to te AWIKONKO lowo lose to koja se so, a gbo pe ojo Wesde ose to m bo yi, iyen ojo keje osu keta la gbo pe o ye ki won se ibura fawon oloye tuntun ti won idibo yan, sugbon ti won ti ye ojo naa.

A gbo pe o seese ki won fofin de awon oloye to ye ki won bura fun yi, ti Sam Owo je olori won, ti ko si ni seni to maa gburo won mo lai lai pelu bi won se so pe awuruju ni won fi yan ara won sipo.

Ohun ti a gbo ni pe won ti yan awon oloye kan lati sagbekale eto idibo miran, eyi ti won so pe gbajumo olorin nni, Sammy B ni olori igbimo naa.

AWIKONKO gbo pe Sammy B to je ojulowo akowe egbe tawon oloye egbe lapapo fun niwe ase ko gbo nipa bi won se seto idibo naa, ti won si fe e fona eburu yo o nipo.

Bo tile je pe laarin bii odun mejo seyin ni won so pe egbe Pman ti ku nipinle Ogun sugbon ta a gbo pe opelope Sam Owo ti won lo tun da pada to si ko awon eeyan jo lati jii dide.

Nibi ti ipade alaafia ti akowe egbe lapapo dari e ti n loo lowo ni wahala ti be sile laarin igun mejeeji ti won si bere si fee maa yowo ese si ara won, o si ku die ki won ju ara won sinu omi legbe ibi ti ipade naa ti waye ni ooteli Ceaser to wa ni Ibara niluu Abeokuta.

Fun bii wakati kan gbako ki won too yanju oro naa, eyi lo sii fa ti Taju System atawon olori egbe lapapo se fa ibinu yo pe ̣peluu bi won se n se yii, won yoo fofin de egbe naa nipinle Ogun.

AWIKONKO gbo pe leyinoreyin lawon oloye egbe PMAN lapapo wa da agbara egbe pada sodo Sammy B ti won si ni ko mu Sam Owo mora lati seto ibo min in laarin egbe naa.

Loju ese si ni won ti ni ki SAMMY B je alaga igbimo to maa seto ibo, awon yooku ti won yoo sise pẹ̀lúu e ni Sego Alaafia, Ogbeni Animasahun, ati Ọ̀gbẹ́ni Oladele Eleganzar.

Peluu gbogbo e  naa, wahala si wa nitori awon onifuji ti so pe awon nipo alaga egbe naa to si gege bi awon se maa n to.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI