Titi di bi e ti n ka iroyin yi loro awon Oloye mefa
n’Ilugun ti won gbe Oba won, Osile Oke-Ona Egba, Oba Adedapo Tejuoso lo siwaju
adajo lori esun wi pe Oba naa ti Ile Ogboni pa.
Bo tile je pe Onidajo Olanrewaju Mabekoje ti ile ejo giga to wa
ladugbo Isabo niluu Abeokuta ti so pe ejo naa ko lese nile, ati pe iron la to
jinna si otito oro lawon Oloye naa lo fi kan Oba Tejuoso, bee lo tun pase wi pe
ki won loo san egberun marundinlogbon (25,000) naira gege bi owo itanran.
Ohun ta a gbo ni pe esun tawon Oloye naa, Raufu Bankole, Jimoh
Alabede, Oladejo Okesipe, Kamoru Adeniran, Ishaq Soyinka ati Ayinde Akintoye fi
kan Oba Adedapo, eyi ti nomba e je AB/151/2014 ni won so pe Oba naa ko lase
lori ile Ogboni to wa ni Ilugun, Oke-Ona Egba depodepo wi pe yoo tii pa, bee ni
won tun so pe ko lase lati ro Oloye kankan nipo.
Lara awon ti won tun fesun kan nile ejo ni Oloye Taofeek Lawal to je
Akinrogun, Oke-Ona Egba, eni ti won loun lo saaju awon ti Kabiyesi ran lati loo
ja Ile Ogboni naa ki won si tun tii pa, sugbon tokunrin naa so pe iro ni won
pa.
AWIKONKO gbo pe se lawon oloye
naa ro ileejo wi pe ko da Oba Adedapo Tejuoso lowo ko lati ma se ni ase lori
Ilugun, paapaa awon Oloye to n lo lati sise, ati pe kenikeni ninu won ma se de
Ile Ogboni naa mo. Bee ni won tun ro ile ejo lati je ki Osile Oke-Ona Egba lo
san milionu mewaa gege bi owo itanran.
Nigba to n gbe idajo kale, Onidajo Olanrewaju Mabekoje so pee sun
tawon oloye naa fi kan Oba Tejuoso ko lese nile, nitori ti ko si eri aridaju
lati fi gbe esun won, to si pase pe ki won loo san egberun marundinlogbon
(25,000) naira gege bi owo itanran.
Nigba to n gbenu Kabiyesi soro, Oloye Taofeek Lawal so pe iro lawon
eeyan naa lo pa niwaju adajo ati pe ilara lo n se won, nitori pea won gan an ni
won da wahala sile.
Okunrin naa so pe kii se pea won loo ti Ile Ogboni naa pa, awon loo si
sile ni, ati pe Oloye Agbejoro Raph Oriade to je Balogun Ilugun lo lewaju awon
iko ti Kabiyesi ran lati loo si sile, nitori pea won ni won tii pa wi pe
kenikeni ma de be.
O ni nigba tawon maa si ile Ogboni naa, awon olopaa atawon eleto aabo
tele awon lo sile lati ri nkan to n sele, ati lati fi won se eleri. Bee lo so
pe awon to n gbe aheso kaakiri wi pe awon oloye ilu naa lo loo si Ili Ogboni
sile ti wa nile ejo Majisireeti, nibi ti won ti n jejo lori esun mejo otooto ti
won fi kan won.
No comments:
Post a Comment