Asiri iku to pa olori ile igbimo asofi ipinle Oyo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, April 28, 2018

Asiri iku to pa olori ile igbimo asofi ipinle Oyo

Titi di bi e ti n ka iroyin yi lawon omi bibi ipinle Oyo si n baraje lori olori ile igbimo asofin won, Onarebu Michael Adeyemo to doloogbe laaro ana ojo Fraide sileewosan ijoba ti Jericho to wa niluu Ibadan.

Bo tile je pe opo awon to gbo nipa iku okunrin oniwa irele naa ni ko tii le so pato iku to pa Adeyemo, eni odun merindinlaadota (46) sugbon ta a gbo pe aisan okan ti a mo si heart attack lo seku pa a, gege bi eni to sunmo on se so.

"Iro ni, ooto ni, ko le je Adeyemo, a si soro lai pe yi" atawon oro iyalenu lorisirisi lawon eeyan n so laaro Fraide nigba tiroyin iku naa bere sii tan kaakiri, ko to o di pe o pada di ooto mo awon eeyan lowo.

AWIKONKO gbo pe se ni Adeyemo deede subu lule laaro ojo naa lasiko to n mura lati lo si ibise. Lesekese la gbo pe won sare gbe e lo si osibitu jenere ti Jericho to wa niluu Ibadan lati doola emi e, sugbon nigba ti won maa debe, o ti ta teru nipa.

Onarebu Kehinde Sabir to je okan lara awon omo ile igbimo asofin ipinle naa nigba to n ba akoroyin ileese Vanguard soro nipa isele naa so pe ibanuje niku olori won je nitori pe iku to pa a ko mu ifura pe bo ya o n saisan dani nitori pe funra e lo si wa moto dele lojo Tosde tawon jo kuro nibise.

AWIKONKO gbo pe lesekese tawon dokita ti jeri sii pe akuko ti ko leyin Adeyemo to je omo bibi ilu Lanlate nijoba ibile Ibarapa East nipinle Oyo ni won ti gbe oku e lo si mosuari.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI