Idagbasoke alailegbe ni mo fe e mu wo ipinle Osun - Enjinia Lawal - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, April 28, 2018

Idagbasoke alailegbe ni mo fe e mu wo ipinle Osun - Enjinia Lawal

Oludije sipo gomina ipinle Osun labe egbe oselu APC lodun 2018 ta a wa yi, Onimo-Ero Ayoade Afolabi Lawal so pe ko si nnkan meji toun fe e mu wo ipinle Osun boun ba di gomina bi ko se awon idagbasoke alailegbe toun ni lokan, eyi to mu koun jade lati dupo naa, ati pe oun mo awon ona toun le fi yi itan ipinle naa pada si bawon eeyan se n fe, ti yoo si je itewogba fun opolopo awon eeyan jake-jado orileede yi, to fi mo oke-okun, latari awon afojusun toun ni nipa idagbasoke gege bi akosemose onimo-ero.

Enjinia Lawal
Enjinia Lawal lo soro yi nibi ipade to se pelu awon oniroyin lojo Fraide ana, nibi to ti so pataki idi to fi fe e jade dupo naa, paapaa labe egbe oselu APC, to si tun so nipa awon isoro to n doju ko ipinle Osun nipa eto oro aje ati idagbasoke.

Lawal to je omo bibi ilu Iwo ni Osun West so pe bo tile je pe idagbasoke die-die ti wo ipinle Osun, sugbon ko tii to bo se ye ko ri pelu oju tawon eeyan fi n wo o. O ni bi won ba fi le gba oun laaye gege bi gomina, itan ipinle Osun yoo si pada nitori awon eto arambara toun ni fun ipinle naa.

"Pataki idi ti mo fi fe e jade dupo ni pe, mo rii pe awon nnkan amusoro ipinle Osun ti ru, eyi to je gege bi ipenija nla, ati pe gege bi onimo-ero, mo maa n nigbagbo pe iru awon ipenija bayii lo maa n mu iru awon eeyan bii ti wa di onimo-ero to se aseyori (successful engineer). Lati wa iyanju sawon ipenija naa lo tun maa n fun wa ni ayo ati idunnu.

"Awon ohun amusoro ipinle Osun po debi pe bi a ba loo sawon ona to ba ye, ko ni si iyato laarin ipinle Osun atawon ipinle to wa kaakiri orileede Naijiria. Mo ni itara latinu wa to jinle (strong passion) fun idagbasoke. Mo si nigbagbo pelu afojusun (optimistic) pe ipenija ta a ni nipinle Osun, fun igba die ni.

"Opo awon eeyan lo je pe won kii wo ti ojo iwaju, nnkan ti won maa ri gba lonii lo maa n je won logun. Wi pe bawon eeyan se n wo ipinle Osun pelu bo se ri lonii, ti ko dun un wo loju bo ti ye, ko tunmo si pe bo se maa ri titi aye niyen. Ti a ba si ni ka wo o, a a rii pe idagbasoke igbalode ti wa lawon eka bii ile eko to dara, biriiji to dun un wo, ona to ja geere.

"Emi gege bi enikan, nnkan to je mi logun ti mo fi fe e dupo naa ni pe, mo fe e yi ipinle Osun pada si eyi ti yoo je itewogba lowo awon eeyan, to je pe orisirisi awon ileese alaseyori ni yoo wole wa, tawon araalu yoo si je anfaani e, ati pe eto oro aje to soju saara, ti yoo yi igba pada lo tun mu ki n ni ero lati jade dupo gomina. Idagbasoke alailegbe ni mo fe e mu wo ipinle Osun pelu opolo ti mo ni gege bi onimo-ero."

Lawal to ko eko nipa Chemical Engineering nigba to n soro nipa eto eko nipinle Osun, o so pe inu oun maa n baje nigba toun ba n wo ipo ti eto eko wa nipinle Osun, paapaa lorileede Naijiria nitori pe ipele eko ta a ni se lo n lo sile sii, kaka ko maa lo soke lojoojumo laarin awon omo wa to n dagbasoke.

"Laye igba kan, o le jeri awon nnkan ti akekoo to wa nipele keta nile eko alakobere (primary 3) le se, sugbon bi e ba pe iru omo be e lasiko yi, iyalenu lo maa je pe omo min in ko le ka onka isiro (time table). Emi gege bi enikan, ti m ba je gomina, pelu imo eko mi, mo ma maa lo kaakiri awon ile eko lati lo maa ko won lekoo isiro.

"Eto maa wa to je pe a ni lati maa se idanilekoo igbalode atigbadegba fawon olukoni lati le je ki won ba eko igbalode mu."

Nigba to n soro nipa iye igba to ni lokan lati je gomina ipinle naa to ba wole, Enjinia Lawal so pe bo tile je pe ofin faaye gba oloselu lati lo leemeji, eyi ti ko ni je koun nii lokan nigba iye igba toun fe e lo.

O ni awon araalu lo lase lati pinnu iye igba toun maa lo nitori pe bi won ba ri awon ise toun ba se lo tun maa fun won lanfaani lati so pe kawon tun fibo won gbe oun wole leekeji.

Nipa oro ise agbe, okunrin naa tun so pe eto ati ilana ti wa nile fun boun yoo se gbe ise agbe laruge nipinle oun, eyi ti yoo mu ki gbogbo eeyan, paapaa awon odo (Youth) naa fe e kopa ninu e, nitori pe ise agbe gan an ni won fi pile orileede Naijiria, toun ko si ni fe ko pare nipinle Osun.

O ni kii se pe ki won gbe oko (hoe) lati so pe awon fe e lo maa lo ara won ninu oko (farm), nitori pe anfaani maa wa fun won lati lo awon irinse igbalode bii tractor atawon nnkan to le mu ise rorun fun won.

Bee lo so pe awon yoo tare owo repete seka ise agbe, tawon yoo si tun gba awon odo sise agbe, ti won yoo maa gba owo osu, tawon naa yoo si tun le da ise tara won sile.

Bakan naa lo bu enu ate lu bawon oloselu se n so pe awon n ro awon odo lagbara, iyen empowerment to je pe okada, keke maruwa, ero ata ni won n ra ti won n gbe fun won. O ni ko ye kiru ero be e wa sokan won nitori pe lo da bi eni pe won fe e so gbogbo eeyan di olokada tabi onise kan naa.

Lawal so pe oun ko figba kan nii lero wi pe iru nnkan toun naa fe e se ni yii nitori pe ile aye ta a wa lasiko yi ti laju ju ki oloselu kan ronu nnkan be e, nitori asiko olaju igbalode (digital era) la wa yi.

O ni ironilagbara kii se pe ki a fun eeyan ni eja je, bi ko se pe ki won ko won bi won se n pa eja. Bee lo fi kun un pe eto wa to je pe awon yoo ko da ileese ti won yoo ti maa ko eko nipa ise owo sile, ti won ko si nii gba owo lowo won, tawon naa yoo si le da duro.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI