Ayeye odun ilu ile Afrika: awon Oba alaye soro - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, April 21, 2018

Ayeye odun ilu ile Afrika: awon Oba alaye soro

Ko seni to de gbagede ayeye asa, iyen Cultural Center to wa ni Kuto niluu Abeokuta lojo Tosde ati Fraide to koja yi, ti ko nii mo pe owo kekere ko nijoba ipinle Ogun fi mu ayeye odun ilu ile Afrika, iyen African Drums Festival nitori pe orileede marundinlogbon (25) nile Afrika, ipinle marundinlogbon ati awon egbe ti ko din ni aadorin (70 troupes) ni won kopa nibe.

Oba Adeyeye Enitan Ogunwusi, Ooni Ile Ife so pe awon omo ile adulawa, paapaa ile Yoruba ko gbodo la oju won sile lati gba ki asa ati ise ti won jogun ba pare mo won loju nitori pe oun nikan ni nnkan amusoro ati amusagbara tawon alawo funfun n wo, ko da ti won tun wa n ko lati mo o.

Ooni lo soro yi lose to koja niluu Abeokuta nibi ayeye odun ilu ile adulawo, iyen Africa Drums Festival eleeketa iru e tijoba ipinle Ogun sagbateru e, o ni ka ma tori olaju to n de gbagbe orirun wa.

Bee lo gboriyin fun Gomina Ibikunle Amosun fun bo se ronu lati gbe iru eto to n polongo ife, isokan ati alaafia laarin ile adulawa kale lodoodun, o ni kii se toro enu pe kaakiri agbaye, ayeye odun ilu yi lo gbajumo ju ninu awon ayeye asa toun ti n ri.

Ninu oro e, Alaafin Oyo, Oba Lamidi Adeyemi je ko di mi mo ilu koja nnkan teeyan kan le maa jo si nitori pe orisirisi nnkan lo wulo fun un, bii ibaraenisoro, owe, ariya ati bee bee lo.

Oba Adeyemi ni boun ko ba a ti gbo ilu laaro, oun kii ji nitori pe asa ile Yoruba ni lilo ilu lati fi gbe Oba dide lori beedi, nitori naa kawon eeyan lo o tun ara won mu lati mo awon pataki asa paapaa ilu, kinwon le maa gbe laruge.

Alake tile Egba, Oba Adedotun Gbadebo ni bi a ba wo ipo ti ipinle Ogun wa lagbaye lasiko yi, a a ri pe won ti sun siwaju nitori pe ayeye odun ilu ile Afrika yi ti mu ki won wa lapa oke ninu awon ilu to n gbe asa laruge.

Obong tilu Calabar, Edidem Bassey Ekpo so pe ayeye odun isu lawon maa n se lodo awon, sugbon eyi tun yato gedengbe si bawon se maa n se, paapaa awon ayeye asa to ku lorileede Naijiria. O loun yoo tiraka lati rii pe oun n polongo ayeye odun ilu yi kaakiri ile adulawo.

Alaaji Lai Mohammed seleri pe ijoba apapo yoo bere sii se iranlowo to ba ye fun ipinle Ogun lati rii pe ayeye yi n tesiwaju lodoodun, nitori pe awon yoo fi sinu onka orileede (country calendar), tawon yoo si tun maa polongo e kaakiri agbaye.

Gomina Ibikunle Amosun ninu oro ti e so pe ko si nnkan meji to mu koun gbe iru eto yi kale, bi ko se lati fi polongo isokan, ife ati alaafia kaakiri agbaye, paapaa ile adulawo.

O dupe lowo awon alejo atawon akopa, to si seleri pe oun yoo je ki ayeye todun to n bo larinrin ju todun yi lo nitori pe oun yoo fun awon ileese aladani laaye lati sagbateru e.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI