FIBAN fee se iranti Gbenga Adeboye ati Toba Opaleye - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, April 23, 2018

FIBAN fee se iranti Gbenga Adeboye ati Toba Opaleye

Bi e se n ka iroyin yi, gbogbo eto lo ti fe e pari fun ti eto iranti awon akoni oloogbe meji nni, Oloogbe Gbenga Adeboye ati Oloogbe Toba Opaleye ti egbe sorosoro to da duro, iyen Freelance and Independent Broadcasters' Association of Nigeria (FIBAN) eka tipinle Ogun maa n sagbateru e lodoodun.

Gege b'AWIKONKO se gbo, ogbon ojo osu ta a wa yi, iyen April 30 ni eto naa maa waye ni gbongan ayeye awon olukoni, iyen NUT Hall to wa ni adojuko papa isere MKO, Kuto niluu Abeokuta laago meji osan.

A gbo pe eto todun yi ti won pe akori e ni "RAISING LEADERS FOR NATIONAL GROWTH - THE PEOPLE, THE MEDIA AND THE UMPIRE" lawon ojogbon kaakiri ti n gbaradi fun lati bu ola fun awon akoni sorosoro meji naa ti won ti file s'aso bora.

Nigba to n gbe iroyin naa si AWIKONKO leti, alaga egbe naa, Komureedi Olufemi Omilani je ko di mi mo pe ara oto ni won fe e gba se eto todun yi pelu awon eto olokan-o-jokan tawon ti la sile f'ojo naa.

Olori ile igbimo asofin ipinle Ogun, Suraju Isola Adekunbi la gbo pe yoo je alaga ojo naa, nigba ti alaga ajo eleto idibo nipinle Oyo, Amofin Mutiu Agboke yoo soro lori koko pataki oro lojo naa.

AWIKONKO tun gbo pe egbe FIBAN tun fe e lo anfaani eto naa lati fun awon eeyan kan ti won ti kopa to joju lawujo ni ami eye, awoodu lojo naa, lara awon ti yoo si gba ami eye naa ni Onarebu Gbenga Adenmosun to je Komisana fun oro agbegbe ati egbe alajeseku; Alaaji Ambali Isola to je akowe agba tele leka ijoba; Komureedi Titilope Adebanjo to je alaga egbe awon oluko nipinle Ogun.

Awon min in ti yoo tun gba awoodu ni Komureedi Akeem Lasisi to je alaga egbe ASUSS; Oloye I. Dagunro to je olori awon ode nipinle Ogun bakan naa.

Pabambari eto naa ni bi won tun se fe e safihan awon ise ti awon oloogbe mejeeji naa ti se sile fungba akoko ninu itan, to si see se ki won ta awon fonran naa lojo naa fawon to ba wa nibe.

Be o ba gbagbe, asiko ti Aare egbe naa, Komureedi Desmond Abiodun Nwachukwu wa gege bi alaga ni won bere eto naa ti alaga ana fegbe naa, Ogbeni Akinyemi Olatoye, iyen Alawiye Fediresan naa si tesiwaju lati ma je ki ise awon to so ise sorosoro di irorun titi di onii di ohun igbagbe.

Ki eto naa ma baa parun lo je ki Komureedi Omilani naa tesiwaju, ti opo awon eeyan jakejado orileede yi si ti n mura sile fun ojo naa, iyen ojo Monde ose to m bo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI