LOBATAN: Awon agbaagba Yewa lawon dariji Osoba - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, April 17, 2018

LOBATAN: Awon agbaagba Yewa lawon dariji Osoba

...Ko si nnkan to kan wa peluu Wizkid Amosun

Lojo Tusde to koja yii lawon agbaagba ile Yewa sare to awon oniroyin lo niluu Abeokuta lati loo yi ohun pada pe awon ti dariji Oloye Olusegun Osoba, awon ko si ba a ja mo, ati pe awon dupe lowo e fun bo se n gbaruku ti awon ni gbogbo igba lori bawon se maa gba ipo akoko nipinle Ogun, iyen ipo gomina.

Be o ba gbagbe, lodun to koja lawon agbaagba ile Yewa yi ti Diakoni Poju Adeyemi to je akowe ijoba ipinle Ogun teleri je adari won so pe odale ni Oloye Olusegun Osoba, ti ko si fe ki ile Yewa depo gomina, bee lo tun n se oju aye sawon.

Sugbon se loro naa yi pada nigba ti won n dahun ibeere ti okan lara awon oniroyin naa beere pe pelu awon oro ti won so kale yi, bawo wa ni aarin won pelu Oloye Osoba bayii pelu bi won se bu enu ate luu nibi ipade ti won bawon oniroyin se lodun to koja.

Nigba to maa dahun, Alaaji Ajibola Olagbaye to lewaju awon agbaagba naa so pe o ye kawon maa dupe lowo awon agbaagba, paapaa awon adari won ni, nitori awon ipa ti won n ko ko kere rara.

Bee ni won tun soro lori omo kekere ti Gomina Ibikunle Amosun loun fe e fa kale, iyen eni to pe ni WizKid, Olagbaye so pe ko si nnkan to kan awon pelu ohun ti Gomina Amosun n so, nitori pe onikaluku lo letoo lati jade dupo.

O ni ko baa je omo kekere (WizKid) ko ba a je agbalagba (Oldkid), onikaluku lo letoo labe ofin lati jade dupo to ba wuu, ti won si kun oju osuwon.

"Gbogbo won ni won ku oju osuwon lati jade dupo to ba wu won. Ko si nnkan to kan wa pelu WizKid ati Oldkid, nnkan to je wa logun ni pe ki eni to ba maa di gomina saa ti je omo Yewa."

Gege b'AWIKONKO se gbo, kii se pe awon agbaagba ile Yewa naa deede gbe ipade pajawiri naa kale pelu awon oniroyin, sugbon won wa lati wa a fi eto ti won n palemo lojo Wesde ojo kejidinlogun osu yi to awon oniroyin naa leti, kawon naa le gbaradi lati wa nibe.

Won ni lati nnkan bi odun meji tawon ti gbe igbimo agbaagba naa kale lawon ti n sise takuntakun lati rii pe awon ipo gomina naa, tawon ko si ko nnkan to le na won, nitori pe lati bii odun mejilelogoji (42) lawon ti n ja takuntakun lati de ipo naa, sugbon to je pe owo Egba ati Ijebu lo n bo si.

Bee ni won so pe awon gbe eto oselu naa kale fawon ojogbon, oloselu atawon ti won fe e jade dupo ninu idibo odun 2019 to n bo lona lati wa a soro nipa nnkan ti won le se fawon eeyan ekun naa, paapaa ipinle Ogun nigba tinwon ba dibo yan won, kawon oludibo le tete mo iru eni ti won yoo tele.


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI