Oluwa Mi: Iyawo mi fesun agbere kan mi, E tuwa ka - Iranse Olorun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, April 18, 2018

Oluwa Mi: Iyawo mi fesun agbere kan mi, E tuwa ka - Iranse Olorun

Bi toko tiyawo ti won tun je iranse Olorun ko ba tete mura si oro ara won ko too di ogunjo osu kerin ti a wa yi, o see se ki ileejo koko-koko to wa ni Ake niluu Abeokuta tu won ka pelu bawon mejeeji se so pe iwa ara won ko ba ara won mu mo, nitori naa, ki ileejo naa tu igbeyawo odun mejo to wa laarin won ka.
Lojo Isegun Tusde ose to koja lo lohun ni iyaale ile naa, Arabinrin Regina Babatunde gbe oko e to je iranse Olorun, Ogbeni Ayinde Babatunde lo siwaju awon adajo, to si n bebe pe ki ile ejo naa tu igbeyawo won ka, bee lo tun be ile ejo pe ko ba oun gba omo kan soso toun bi fun oko oun lowo e.
Nigba to n ka awon esun to fi kan oko e niwaju awon adajo mejeeji, iyen Oloye Akande O.O ati Onarebu Arabinrin Majekodunmi H.I, Regina so pe iwa toko oun n hu soun ko ba toun mu mo, ti ara oun ko si gba a mo gege bi obinrin, nitori pe opo igba lo maa n lu oun, ti ko sit un ni foun lowo ounje.
Iyaale ile eni odun mejilelogoji (42) to so pe ile ounje igbalode kan loun ti n sise naa tun so pe igba kan wa ti oko oun ti le oun jade fojo meta ri, to je pe odo araadugbo loun lo sun, ki won too ba won pari e, bee lo so pe oko oun tun le oun jade fosu meta, ti ko beere laafia oun ati omo oun, o lawon ebi lo bawon pari e.
Obinrin naa so pe nnkan to tun fa a toun fi wa sile ejo ni bi oko oun se le oun jade kuro nile, to si gba omo lowo oun, to lo gbe e fun un awon obinrin meji kan, Bose ati Funmilayo ti won kii se ebi e rara, tawon yen si n fiya je omo oun, ko da to so pe Funmilayo ti fe e na oun lojo kan nitori toun loo wo omo naa nile won.
Nigba toun naa n soro, Baale ile naa to so pe iyen Salesman loun n se so pe nigba toun fe Regina loun ti ba Olorun da majemu pe oun ko nii ko enu ife si obinrin miran laye oun mo, to si je pe Olorun le jeri oun.
Ayinde so pe esun tiyawo oun fi kan oun ni pe nise loun n yan ale, ko da, to tun so pe oun ti bimo sita. O niyawo oun ti loo fejo sun aburo oun kan to n gbe l’Ekoo, to si tun n ba oun loruko je kaakiri pelu boun se je iranse Olorun.
Okunrin naa so pe nigba ti wahala naa maa koko bere, aburo iyawo e lo so pe o fee se idanwo asekagba, iyen WAEC, toun si so pe ko je komo naa wa maa gbe lodo won, sugbon tiyawo oun so pe se loun n ba omo naa sun.
Nipa awon ti Regina so pe omo wa lodo e, Ayinde ni ile Bose ati Funmilayo loun gbe nigba toun lo sise niluu Ibadan, nibe loun ti mo won ti won si se daadaa soun, lo je koun mu omo naa lo sodo won lati maa gbe, toun si lo n fomo naa lowo ounje ni gbogbo ipari ose.
Awon onidajo mejeeji, Oloye Akande ati igbakeji Onarebu Majekodunmi nigba ti won n beere pe kin i won fe e, se lawon mejeeji so pea won ko le pada di loko-laya mo lailai, nitori konikaluku maa lo.
Oloye Akande ati igbakeji e so pe bo tile je pe ofin ko faaye gba won lati tu won ka lojo kan soso ti won ba koko gbe ejo wa, sugbon ki won pada wa logunjo osu yi, bi ko bas i ayipada, awon yoo gbe igbese to ba ye.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI