Owo olopaa ipinle Ogun te ore meji to n jale - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, April 29, 2018

Owo olopaa ipinle Ogun te ore meji to n jale

Nise lorin ope gba enu awon araalu Abeokuta lojo Abameta Satide ana nigba ti owo awon olopaa te gendekunrin meji ti won ko nise meji ju ole ji ja lo, leyin ti won loo fipa gba okada kan lowo eni to nii.

Gege b'AWIKONKO se gbo losan onii, ojo Wesde to koja yi, iyen ojo karundinlogbon osu ta a wa yi ni won so pe gendekunrin meji naa, Evans Ajao to je omo ogbon odun (30) ati ore e, Isaiah Aigba omodun mokanlelogun (21) fipa gba okada Bajaaji (Bajaj) lowo eni to nii ni nnkan bi aago mefa koja iseju meedogbon irole (6:25pm) lagbegbe Alabata.

A gbo pe olokada naa ta a ko tii moruko titi dasiko ta a sakojopo iroyin yi tan lo loo foro naa to oga olopaa to wa ni Odeda, Ogbeni Muhammad Baba Sulaiman leti, to si pase pe kawon omose e wa awon odaran naa lo.

Ohun ta a tun gbo ni pe asiko ti won n gbiyanju lati loo ta okada naa si orileede olominira Benin (Republic of Benin) lowo te won ni abule Baagbon nijoba ibile Odeda.

Bi owo se te won ni won ti bere sii ka boroboro fawon olopaa pe o ti pe tawon ti n ja okada gba lowo awon eeyan, to si je pe bawon ba ti gba a, orileede olominira Benin lawon maa n ta a si lodo awon onibara a won.

Iyen nikan ko, a tun gbo pe se ni ogbologbo adigunjale kan naa ba iku ojiji pade lojo Abameta Satide ana lakoko toun naa n gbiyanju lati na papa bora leyin to fibon gba okada lowo eni to nii, iyen Toyin Ayoade.

AWIKONKO gbo pe ni nnkan bi aago marun un ku iseju meedogun irole (4:45pm) ni adigunjale naa pe Toyin gege bi olokada pe ko gbe oun lo si adugbo Sabo, bi won si se de abule kan ti won n pe ni Ijaye nitosi Lafenwa lo ba yo ibon ilewo kekere kan jade.

Ere la gbo pe Toyin koko pe nigba ti gendekunrin naa so pe ko gbe okada naa foun, nibi ti won ti n se agidi ni odomokunrin naa ti yinbon fun Toyin lowo to si subu lule sinu agbara eje.

Awon to wa nitosi ti won gbo iro ibon la gbo pe won sare lati loo ba won, sugbon ki won to de be, odomokunrin jaguda naa ti fese fe e pelu okada, bee ni won tele e lati muu.

Nibi to ti n salo ni won loo ti subu sinu kota pelu okada naa to si fi ori gba ogiri kota, lesekese lo ti ta teru nipa, ti won si ranse pe awon olopaa lati wa a gbe oku e.

Nigba to n jeri sawon isele naa, Abimbola Oyeyemi to je agbenuso olopaa je ko ye AWIKONKO pe looto ni, ati pe awon meji towo te si wa logba SARS ti Komisana won pase pe ki won ko won lo lati tubo foro wa won lenu wo.

Bee lo so pe Toyin ti won yinbon fun si wa ni osibitu to ti n gba itoju lowo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI